Owo te baba agbalagba to n jale - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 12, 2018

Owo te baba agbalagba to n jale

...Odun keedogun ti mo ti n jale re e - Lateef

Opo awon to gbo bi Baba agbalagba tojo ori e ti le ni aadota odun, Lateef Folami se n soro logba FSARS to wa ni Magbon niluu Abeokuta lose to koja yi ni won n rawo ebe sijoba pee won gbere ni ki won da fun un, nitori pe bi won ba tun fi sile, bii igba ti won tun fe ko tun maa tesiwaju ninu ise ole jija, ko si maa pawon eeyan lekun jaye ni.

Lateef
Ohun ta a gbo ni pe, ogbologbo adigunjale ni Lateef, o si ti le lodun meedogun (15years) to ti wa lenu ise burku naa, to si ti gba ibi ise naa dero ogba ewon leemeeji otooto.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, awon gendekunrin kan la gbo pe won lo roobu banki kan ta a foruko bo lasiri lagbegbe Agbara nipinle Ogun lose to lo lohun, nigba tawon yen n na papa bora la gbo pe won ko sowo Lateef ati okan lara awon omose e, Benjamin Oforitse, omo ogun odun.

Lesekse la gbo pe Lateef ti yo ibon si won, ti won si gba owo naa to to egberun lona oodunrun (500,000) naira lowo won pelu okada, ti won si salo, nibi ti won ti n salo la gbo pea won araalu ti won ti firoyin naa to leti ti rowo to won, ti won si fawon le awon olopaa lowo lesekese.

Nigba to n ka boroboro, Lateef so pe opo awon tawon jo n jale ni won ti pade iku ojiji lenu ise yi, to si je pe ori lo maa n ko ohun yo, bo tile je pe asiri ohun maa n pada tu, toun si ti sewon leemeeji otooto.

Ninu oro e, O so pe “Odun keedogun ti mo ti n jale re e, eemeji otooto ni mo si ti sewon basiri ba tu. Odun mefa ni mo koko lo logba ewon, ti mo si tun lo odun meji leekeji. Nigba towo maa koko te mi, eran agbo ni mo loo ji gbe ni iteku to wa nitosi tesan olopaa Badagry, ibe lowo tit e mi, ti won ran mi lo sewon odun mefa.

“Eleekeji, mo gbe awon meji lori okada lati agbegbe Alaba lo si Bariga, mi o mo pe ole lawon yen naa n ja, igba ta a maa de agbegbe Charlie Boy ni won gbiyanju lati ja baagi gba lai mo pea won eso alaabo wa nitosi, awon ni won le wa, towo si te emi ati Wale, ti eni keta na papa bora. Tesan agbegbe Pedro ti won ko wa lo la ti foju bale ejo, ile ejo naa la gba de ogba ewon Ikoyi.”

Nigba towo maa pada te won, o je ko ye wa pe lojo keji osu yi loun ati Benjamin jade lati tun loo jale, tawon si ri awon kan to n jade lati inu baanki pelu owo ninu baagi, nigba tawon si ja baagi naa gba, tawon n salo lai mo pe won ti tawon araabule Idonyin/Edun, nitosi Agbara tawon gba lolobo, oju ona lo so pe owo ti te Benjamin, ojo keji lo so pe owo pada te oun.

Yato si Lateef ati Benjamin towo te, a gbo pe owo olopaa SARS tun te gendekunrin meta, Yusuf Owoyele, eni odun merinlelogbon (34), Tunde Owoyele, eni odun metalelogun (23) ati Itunu Abisoye, omodun mejilelogun (22) ti won ni afurasi ni lawon meteeta, sugbon ti gbogbo won si n gbategun logba SARS digba ti won yoo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI