Se ni idunnu
subu lu ayo awon omo ipinle Eko ati Ekiti nigba ti won gbo pe Gomina Ayodele Fayose
ati Gomina Akinwunmi Ambode ti joo towo b’owe adehun (MoU) lori ona ti won yoo
gba lati maa gbin iresi (rice), eyi ti yoo mu ki ounje po jaburata fawon araalu
lati maa ri je lasiko.
Titi di bi e
ti n ka iroyin yi lawon omo ipinle mejeeji yi, iyen Eko ati Ekiti si fi n ki
awon gomina won fun asoyepo naa.
Gege b’AWIKONKO
se gbo, ori ero ayelujara ni Gomina Ayodele Fayose ti soro naa sita lojo Tosde
to koja yip e igbadun ti de fawon omo ipinle mejeeji yii, ati pee to oro aje
won yoo tubo gbe peeli sii.
Gomina
Fayose so pea won ti setan lati pese awon ile (land) ti won yoo gbin awon iresi
naa si, to si je pe ijoba ipinle Eko ni yoo pese awon eso iresi ati owo ti won
fe e lo.
No comments:
Post a Comment