...Yayi kii se iberu fun mi - GNI
Ko din ni egberun mewaa awon omo egbe oselu to n satileyin fun Seneto Solomon Olamilekan Adeola tawon eeyan mo si Yayi, eni to fe e jade dupo gomina ipinle Ogun legbe oselu APC lodun 2019 ni won tii so pe Omoba Gboyega Nasiru Isiaka lawon n ba lo bayii.
Orin maa jo lo awa leyin e digbi ni won n ko bayii fun Omoba Gboyega Nasiru Isiaka ti egbe oselu ADC wi pe oun gan an lawon fe e satileyin fun lodun to n bo, kii se Yayi tawon ko tii mo ipo e ninu egbe oselu APC.
Alaaji Moruf Ajisegiri to je okan pataki to n satileyin fun Seneto Yayi lo soro naa pe awon ko tele okunrin kukuru naa mo, nitori pe GNI lawon nife sii lati tele lodun to n bo.
Awon eeyan naa lo je pe kaakiri Ogun mefa to wa ni Aarin gbungbun ipinle Ogun (Ogun Central) ni won je, to si je pe Alaaji Ajisegiri lo ko won leyin.
Lara awon to tun wa nibi eto naa ni Alagba Joju Fadairo to je alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun tele, Ogbeni Adeniyi Adebanjo to je alaga egbe ADC to fi mo awon agbaagba egbe naa.
Ninu oro ti e, akowe tele nijoba ibile Abeokuta South, Nurudeen Olaleye so pe ko si nnkan meji to mu kawon kuro leyin Seneto Yayi bi ko se awon nnkan tonn dojuko okunrin naa nipinle Eko, to si je pe ese tun si n mi nipinle Ogun nibi, to si je pe awon ko fe e padanu ona meji.
Ajisegiri nigba to n fowo soya lori GNI so pe oro okunrin naa ti su awon alatileyin e, nitori pe oju kan soso lawon wa lati ojo yi latari bi ko se finu han won lori ipinu e laarin ipinle mejeeji to n le.
O lawon ti setan lati gba ipo gomina naa fun Gboyega Isiaka nitori pe oun gan an leni tawon n fe tokan-tokan, to si je pe ko seni to le kegbe e laarin awon adije to ku.
Gboyega Isiaka ninu oro ti e so pe aaye sile fawon to ba fe e dije dupo lodun 2019 ninu egbe oselu ADC, ko da to fi mo ipo gomina nitori pe eru ko ba oun.
O ni ki won koo ranse pe Seneto Yayi pe ko wa a darapo mo won lati ba oun figagbaga idibo abele, oun setan lati maa figagbaga nitori pe kii se eru foun rara.
GNI ni se loro naa da bi eni to ti n gba boolu tipe ati eni to sese fe maa gba boolu, nitori pe se loun yoo feyin gbole ninu idibo abele, iyen to ba wa a darapo mo egbe ADC.
Bakan naa lo tun so pe aaye ipo ogoji lo si sile fawon omo naa lati di ninu idibo to n bo naa, bee lo gbawon eeyan nimoran pe ki won tete lo anfaani osu kereje to ku yi lati fi loo gba kaadi idibo alalope PVC won ko too pe ju.
No comments:
Post a Comment