O Tan O: Awon Yewa Lawon Satileyin Fun Adebutu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 27, 2018

O Tan O: Awon Yewa Lawon Satileyin Fun Adebutu

Lojo Monde to koja ni Onarebu Oladipupo Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asoju-sofin kekere niluu Abuja teko leti lo silu Ilaro pelu iko akowo-rin e lati loo derin peeke awon eeyan to wa nibe.


Gege b'AWIKONKO se gbo, se ni idunnu subu lu ayo awon eeyan naa nigba ti Onarebu Adebutu toun naa n foju sona lati jade dupo gomina ipinle Ogun labe egbe oselu PDP lodun 2019 to n bo yi.

Ohun ta a gbo ni pe awon ara agbegbe Ogburu, Ajilete ati Folasade-Oke Ogbun to wa niluu Ilaro, labe ijoba ibile Yewa South lawon ti won ko le gbagbe ojo karundinlogbon osu kefa, odun 2018 naa pelu ero amunawa ti agbara e ko din ni eedegbeta (500KVA).


A gbo pe eto ti won se lati fi fawon eeyan naa ni ero amunawa ni lati fi fa oju awon eeyan mora fun ti idibo gomina to n bo lodun 2019, ati lati loo sabewo sawon awon omo egbe naa kaakiri ijoba ibile to wa ni Yewa South.

Nigba to n soro, Onarebu Adebutu kanminu pupo lori bawon eeyan naa ti se wa ninu okunkun lati odun to ti pe seyin, eyi to loo ti sakoba fun eto oro aje won nibe.

Adebutu ni ero amunawa naa yoo je ki eto oro aje won nibe ji pada, ti yoo si tun je ona abayo fun idase sile lawon agbegbe naa, tawon odo naa yoo si tun maa ri ise se.


Nigba to n gba enu awon agbaagba Ajilete soro lati dupe lowo Onarebu Adebutu, Oloye Falae Ayinde to je Bada ilu Ago Ilaro Ajilete, eni to tun je akowe ilu naa dupe lowo Onarebu naa, to si so pe aanu to n se kaakiri origun mereerin ipinle yi ko ni elegbe.

O loun mo pe bi Adebutu ba wole gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019, gbogbo awon omo ipinle naa ni yoo je anfaani e nitori pe aanu to fi n han sawon eeyan kaakiri, ko nii se pelu oro eleyameya rara.

Ohun ta a tun gbo ni pe ko igba din l'egberun meji lawon omo egbe oselu APC ti won lawon setan lati satileyin fun Onarebu Adebutu, iyen nibi ipade ti won se lagbegbe Oke-Odan.

AWIKONKO tun gbo pe yato si pe won korin yin Onarebu Adebutu lojo naa, won tun fun Onarebu naa lebun aworan e ti won ti ya oun funra e si. Diakoni Olaniyi Jonathan to je alaga ijoba ibile Yewa South tele la gbo pe o saaju awon eeyan naa lo ba Adebutu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI