Nitori Super Eagles: Paseda Sayeye Ojo Ibi E Fawon Oniroyin L'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 23, 2018

Nitori Super Eagles: Paseda Sayeye Ojo Ibi E Fawon Oniroyin L'Abeokuta

Adije sipo gomina ipinle Ogun, Omoba Olarotimi Olatunde Paseda se ayeye ojo ibi e fawon oniroyin ipinle Ogun niluu Abeokuta lonii ojo kejilelogun, iyen Fraide.


Eto ayeye ojo ibi naa ti won se ninu ogba awon oniroyin to wa ni Oke-Ilewo, Abeokuta ni won se ni nnkan bii ago mefa irole pelu awon ololufe e gbajumo onisowo naa, iyen Omoba Paseda.

Nibe ni alaga egbe akoroyin nipinle Ogun, Komureedi Wole Sokunbi ti je ko di mimo fun Paseda, eni ti Onarebu Arabinrin Yemi Layeni to je alaga egbe awon obinrin to n satileyin fun Paseda soju fun pe awon kii se oloselu.

Komureedi Sokunbi so pe bo tile je pe awon kii se oselu, tawon ko si lee fa owo oloselu kan soke, sibe, iyen ko so pe kawon ma satileyin to ba ye fun oloselu to ba wa a ba won nipa oro iroyin.

O tesiwaju pe ko si egbe oselu naa tawon kii ba se nitori pe ore awon oloselu lawon oniroyin, ati pe gbogbo oloselu to ba wa a ba won fun iranlowo nipa gbigbe iroyin jade lawon n satileyin fun lai se oju saaju.

Lakotan, Sokunbi dupe lowo Omoba Paseda fun ife to ni si egbe naa, pelu bo se ka won kun lati wa a sayeye ojo ibi naa fun won.

Ninu oro tie, Onarebu Arabinrin Layeni so pe bo tile je pe oga oun ti koko wa sinu ogba naa lati se ayeye naa fun won, sugbon nitori pe pupo ninu awon omo egbe oniroyin ni won ko si nitosi, eyi lo mu ki oga oun, Paseda tun sare lo sibi min in to si seleri fun won.

O ni Paseda foro ikinni ranse segbe oniroyin fun atileyin won ni gbogbo igba, bee lo tun so pe oga oun ti pinu lati mu ojo min in lati jokoo papo pelu awon oniroyin.

Lara awon to tun wa nibi ayeye rampe naa ni Enjinia Matthew Folarin to je adari ajo Paseda (DG, Paseda Legacy Foundation).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI