MOTO YA PA AWON META NI SIUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 9, 2018

MOTO YA PA AWON META NI SIUN

Orin ikunle abiyamo lo gba enu awon to n koja lagbegbe Adedero, loju ona Siun si Abeokuta lojo Wesde ose to koja yi nigba ti won ni moto ayokele Honda kan ti nomba idanimo e je EPE 697 AU loo ya pa awon meta kan nibi ti won duro si jeje won.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni ilu Abeokuta lawon meta naa n lo ko too di pe ijanu moto ayokele naa ja danu, nibi yi awako naa si ti n du bi yoo se duro lai si wahala lo ti lo ya pa won legbe titi nibe, tawon meteeta si ku lesekese.

Ohun to je kayeefi ni bi won se tun so pe se ni awako naa salo, ti ko duro rara nigba to rii pe emi eeyan meta ti towo oun bo, to si see se ko koun sinu wahala nla.

Loju ese la gbo pe awon yo sunmo ijoba pelu awon olopaa ti tawon olopaa to n ri si isele pajawiri (Quick Respond Squard) to n duro siwaju enu ona abawole ofiisi gomina ipinle Ogun lolobo, tawon yen naa si loo duro de awako naa.

Bi won ti se rii to yo lookan ni won ti loo da a duro, ti won si bere sii beere orisirisi ibeere lowo e, bo tile je pe ko koko fe e jewo, sugbon nigba tawon toro naa soju won debe ti won si so bo se sele lo ba bere sii bebe pe ki won se oun jeje.

AWIKONKO gbo pe awon osise ajo eso oju opopona tijoba ipinle Ogun, TRACE lo gbe awon oku naa lo si mosuari tijoba to wa ni Ijaye, ti won si tare awako naa ta a ko tii moruko titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan atawon meji to wa ninu moto pelu e lo si tesan olopaa (MTD) to wa ni Ibara.

Nnkan to tun n ya awon eeyan lenu ni pe ibi ti awako naa pa awon meta won yii si ni okan lara awon oga olopaa nipinle Ogun, Insp Azeez Ajasa padanu emi e si nibere osu karun to koja yi.

Ajasa la gbo pe se ni moto Gulf funfun e ti nomba e je EKY 631 BB gbokiti wonu igbo, to si gbabe soda sorun alakeji ni nnkan bi aago mokanla aabo aaro ojo naa to bo si Wesde.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI