MI O LE BAWON S'EGBE OSELU PDP MO - GNI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 1, 2018

MI O LE BAWON S'EGBE OSELU PDP MO - GNI

Yinka Awobajo

Adije sipo gomina ipinle Ogun leemeji otooto labe egbe oselu PPN ati PDP, Omoba Gboyega Nasiru Isiaka ti so pe ko si nnkan toun tun un wa mo ninu egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP nitori toun ti ri egbe oselu tuntun ti yoo gbe oun de ibi toun n fe.


Gboyega Isiaka tawon eeyan tun n pe ni GNI lo soro yi lonii ojo kinni in osu kefa lakoko to n farahan awon oniroyin, to fi mo awon araalu pe inu egbe oselu tuntun to ni afojusun rere, iyen African Democratic Congress, ADC loun n ba lo.

O ni bo tile je pe egbe oselu PDP loun ti koko wa, ko too di pe oun lo sinu egbe oselu PPN, toun ti ba jade dupo akoko, sugbon toun padanu soso Gomina Ibikunle Amosun lodun 2011, sibe oun tun pada wa nigba ti won tun pe oun pada.

GNI to ti figba kan ri je alakoso ileese to n sabojuto owo ipinle Ogun, iyen Gateway Holdings Limited ni odun 2004 loun bere sii di gbajumo, iyen lakoko isejoba Gomina ana, Otunba Gbenga Daniel, OGD.

Ninu oro e, o so pe "Awon ajalu ti mo ti ba pade ninu oselu seyin, owo mi lo ti wa nitori afojusun ati igbagbo mi ni pe ki agbegbe dara gbodo ko ipa to joju nigbesi aye awon eeyan.

"Emi atawon iko mi ninu igbagbo yi ti se opolopo ipinu, to si ti bi orisirisi iwe eri, sugbon ju gbogbo e lo, mo dupe lowo Olorun lonii. 

"E maa ranti daadaa pe mo gbe apoti ibo ninu egbe kan lodun 2011, sugbon nitori egbe naa to pin lo ba ipinu naa je. Egbe wa  pelu opolopo abewo ati amonran, a lo sinu egbe oselu PPN ti mo ti jade dupo gomina. Leyin idibo odun 2011, a lo osu bii meloo kan lati fi ronu awon nnkan to mu wa padanu. Eyi lo je ka mo pe ategun lasan ni egbe oselu PPN je fun wa, ti ko si le mu wa de ile ileri.

"Abajade e lo je ka loo darapo mo egbe oselu Labour (Labour Party), ti a to bi omo, to si di itewogba fawon araalu sugbon ti kadara tun gba ibomin in yo si wa. Nigba to ku die ki odun 2014 pari ni ase wa lati oke pe ki atunse ati atunto wa laarin awon egbe oselu, ki a si jo fowosowopo, eyi lo tun mu wa pada sinu egbe oselu PDP ti mo tun pada ba jade dupo gomina.

"Pelu awon nnkan ti oju mi ti ri atawon eko ti mo ti ri ko, mo fe e fi asiko yi dupe lowo Otunba Gbenga Daniel to je gomina ana ati Seneto (Omoba) Buruji Kasamu fun bi won se gbaruku ti mi, paapaa julo awon to tun gbaruku ti mi ti mi o le daruko tan.

"Be o ba gbagbe, ojo kerinlelogun osu karun (May 24) to koja yi ni mo kowe pe mi o se egbe oselu PDP mo, latari awon wahala ita ati abele to n sele ninu egbe naa, paapaa nipinle Ogun, ti won ko si wa nnkan se sii. Eyi to se koko ju ni pe egbe naa ko faaye sile fun ipinu ati afojusun ti a ni ninu egbe The Believe Movement, TBM paapaa emi ti mo tun mu irapada wa sinu egbe naa.

"Fun emi Gboyega Nasiru Isiaka gege bi enikan, mi o tun le gba lati dale (betray) awon eeyan mi, awon omo ipinle Ogun, eyi to fa egbe tuntun ti mo darapo mo. Mo ti gba imo ati imisi Olorun, ti mo si tun ti loo sabewo abele pelu imonran lowo awon oloselu, awon ore mi, awon eeyan jannkan-jannkan, awon to wa nigboro, to fi mo awon molebi mi. Mo fe e kede sita, ki n si fi kaadi omo egbe han pe mo ti darapo mo egbe oselu ADC lati onii ojo kinni osu kefa, odun 2018.

"Mo gbawon omo ipinle Ogun, paapaa awon omo orileede Naijiria lamonran pe ki won darapo mo egbe oselu ADC gege bi ona abayo kan soso to se e fokan tan."

Ninu oro ti e, alaga apapo fegbe ADC lorileede Naijiria, Oloye Ralph Nwosu so pe edun okan lo n je foun tele nigba tawon da egbe oselu ADC sile lodun 2006, to je se legbe oselu CPC gba ilana naa mo won lowo, sugbon ti egbe oselu ACN naa tun gba.

Nwosu ni iyalenu lo tun je foun nigba toun tun rii pe agbekale awon ni mu tun mu wo inu egbe oselu APC, to si je pe awon gan an lawon koko soro ayipada (Change) ti won n pariwo lonni.

O ni inu oun dun pe iru eeyan bii Oloye Olusegun Obasanjo lo tun pada ji egbe naa dide, to si ti n je itewogba fawon araalu nitori toun mo pe Olorun ti lowo sii.

Lara awon to wa nibi eto naa ni alaga egbe naa nipinle Ogun, Oloye Adeniyi Adebanjo; Jenera Ekundayo Opaleye; Elda Joju Fadairo; Basorun Niyi Salako; Oloye Arabinrin Mary Ogunjobi; Alaaji Saka Isiaka; Oloye Pegba Otebolu; Otunba Adekunle Adepitan; Majo Orekoya; Oloye Samuel Elegbede atawon min in.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI