To ba di ojo kesan an osu to m bo ti Ogbeni Akeem Wahab ko ba mu
anti e to so pe won le ba oun toju omo to fe e gba lowo iyawo e dani, o see se
ki ile ejo koko-koko to fikale sadugbo Ake Abeokuta ma pada gbe omo naa fun un,
ati pe bi obinrin naa ba tun je eni ti ko karamasiki ojo iwaju omo, ile ejo naa
tun le ma gbe omo e, Basit naa fun un.
Bo tile je pe akoko re e ti toko-tiyawa naa yoo ro ejo won ni
kootu, sugbon lojo Tusde ose to koja ni Baale ile naa, Ogbeni Akeem to ni moto
boosi akero loun n wa so pe ko seni to le be oun pe koun gba iyawo oun,
Bilikisu pada pelu bo ti se yan agbere laayo, toun si ti ka a ko pe lu
orisirisi okunrin lai moye igba.
Akeem ni ko tii ju osu kan lo tawon ni gbolohun aso kekere ninu
ile, to di pe Bilikisu ko eru e jade, to si je pe se ni okunrin min in lo gba
ile fun ladugbo Oke-Lantoro niluu Abeokuta.
O so pe ore e oun kan to n gbe inu ile ti ale gba funyawo oun lo
tu asiri naa soun lowo, toun si loo fidi e mule nigba toun de be, iyen lodun
meje seyin.
Baale ile to so pe oun ko niya ati baba mo ni, nnkan to tun n je
kayeefi ati iberu foun ni pe latigba toun ti so pe oun fe gba omo oun niyawon
oun ti n lepa emi oun, to je pe Olorun lo si n ko oun yi titi dasiko toun fi n
soro. Bee lo so pe bi moto toun n wa ko ba ti e foun laaye lati bojuto omo oun,
anti oun wa nitosi to le maa ba oun toju e daadaa, bo tile je pe ko si nile ejo
lati farahan nitori pe ara e ko ya.
Bilikisu ni ti e so pe iro patapata ni oko oun n pa pe oun ni
egbon kan to le ba a toju omo nitori pe anti e to n so yen ti dagba, ise
alajapa lo si n se, ti kii raaye lati bojuto omo to bi ninu ara e depodepo pe
yoo toju omolomo bi omo oun.
O ni kile ejo ma se gbo awon awijare iro to n so lenu nitori pe
ijapa gan an ni oko oun, ati pe anti e to so pe ara e ko ya yen wa nibi to ti n
sise ajapa nitori ola (Wesde) je ojo oja Kuto ni ko se le wa.
Bee lo tun so pe oun ko le gba ki won je ki omo oun di eni to n
kiri oja kaakiri igboro, nitori pe ojo ola e lo se pataki soun, toun si setan
lati ran lo sile eko titi ti yoo fi jade.
Baba iyawo nigba toun n so tenu e so pe looto lo je pe Akeem lo
ni omo, toun ko si so pe ko ma gba omo e, sugbon kii raaye fenikeni latari ise
de-toru-toru to n se.
No comments:
Post a Comment