ISOKAN ESIN LO SE PATAKI - ADEBUTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 18, 2018

ISOKAN ESIN LO SE PATAKI - ADEBUTU

Onarebu Oladipupo Adebutu ti gbawon Musulumi ati Kirisiteni lamonran pe ki won fi ife ba ara won lo, ki won si ma se je ki iyapa sele laarin awon elesin mejeeji, paapaa bi Aawe Ramadaani se pari yi.


Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja lo soro yi ninu oro ikinni to fi ki awon Musulumi jakejado orileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun lopin ose to koja yi, eyi to fi eda e ranse si AWIKONKO.

O ni isokan esin lo se pataki julo ninu awon nnkan to n mu idagbasoke ati ilosiwaju ba orileede, nitori naa, kawon elesin mejeeji fowosowopo lati gba alaafia laaye laarin ara won, ki won ma si maa wo pe esin kan ni Olorun tewogba, esin kan ko ni Olorun fowo si.

Ninu oro naa lo ti so pe "Eyin ara, pelu ayo ni emi, Qamorudeen Oladipupo Olatunde Adebutu fi n ba a yin sajoyo fun ti emi tuntun ti a sese gba nipase anfaani ati ore ofe ti a ni latari ti aawe Ramadaani to sese pari yi.

"Nipase igbagbo, a ni lati gbagbo pe a ti gbe apoti ese ti segbe kan, nitori naa, o se pataki ka wo inu odun tuntun pelu afojusun lati ni ife atokan wa, ife alailabawon to so pe 'feran enikeji re gege bi ara re.

"Nikorita yi, a ni lati lo anfaani ife ti Olorun ni si wa, ati aanu to fi han si wa  lati maa fi ba ara wa lo po, ati pe awon ti Olorun fun ni anfaani lati lo ogorun odun, yoo tun lo egbeegberun odun lajule orun."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI