Bo
tile je pe ko ju odun meji lo ti toko-tiyawo, Arabinrin Remilekun Familusi ati
Ogbeni Olayinka Familusi ti won bimo kan soso funra fi jog be, sibe wahala ojoojumo
dagbere fawon mejeeji, eyi lo fa a tiyawo fi gbe oko e lo si kootu pe ki adajo
tun won ka.
Iyaale
ile naa lo gbe ejo lo si kootu kokokoko to wa ni Ake losu to koja, ojo Wesde to
koja yi si ni ileejo tu igbeyawo to wa laarin won ka, nigba tawon mejeeji so pe
ife to wa laarin awon ko tun le pada ji mo.
Remilekun,
eni odun marundinlogoji (35) to ni osise ijoba loun se, nigba to n soro so pe “Odun
kefa re e ti a ti pade, odun 2013 ni mo bimo fun un, ko si ju odun meji lo ti a
fi tuka, nitori awon iwa to n hu ko ba temi mu mo loje ki n kuro lodo e.
“Igba
ti mo kuro lodo e, o so fun mi pe oun ti feyawo min in, iyawon yen si ti bimo
meji foun. Gbogbo igba lo maa n pe mi lori foonu, to si ma maa dunkoko mo mi,
to tun ma maa fi atejise buruku si mi lati maa fi dunkoko mo mi. e gba mi lowo
e o.
“O
lo si ileewe omo mi, to lo so fun won nibe pe ileeso ti so pe koun wa maa woo
mo., awon yen so fun un pe awon ko le gba nitori pe oun ko lo mu omo wa fawon. Mi
o fe mo, ko si le gba omo mi lowo mi. mi o tun fe ko ba mi gbe bukata lori omo
mi. E dakun, e ba mi kilo fun pe ko ye e wa sile mi mo lati wa maa ba mi ja, ko
sit un ye e pe foonu mi mo.
Baale
ile naa, Olayinka nigba toun naa n soro so pe iro patapata gba a ni iyawo oun
pa, ati pe ko sese maa pa iro moun, ti ko si je tuntun. O ni Remilekun gan an
ni oniwahala to n da nnkan ru, to si je pe tinu e lo maa se.
Olayinka
ni “Emi lo ye ki n koko gbe e wa si kootu, sugbon baba e to jokoo yi lo so fun
mi pe ki n ni suuru, lai mo pe oun naa ti ni lokan. Lojo ti mo lo si ileewe,
iwe ti mo fi san owo (receipt) ni mo loo gba. Mi o so pe ki omo mi ma duro lodo
e, sugbon nnkan ti mo fe ni pe ko je ki n maa foju kan omo mi lasiko to ba wu
mi.
“Se
lo maa n gbe omo mi pamo fun mi, ti ko fe ki omo naa wa sodo ebi mi. Kii fe ki
omo naa ba mi sere rara. Awon ta a jo n gbe adugbo ti mo n gbe maa n ro pe
okobo ti ko le bimo ni mi pelu ojo ori mi yi. Ko si wahala to ba je ki n maa ri
omo mi lasiko to ba wu mi.
Leyin-o-reyin
tawon mejeeji fi bibeli bura niwaju awon adajo, Oloye Akande O. O to je Aare
ile ejo naa, ati igbakeji e, Onarebu Arabinrin H Majekodunmi H. I so pe ko si
ofin naa lagbaye to maa so pe ki baba omo ma foju kan omo e lai je pe o ti ku,
nitori naa ki Remilekun loo gbagbe pe oun ko fe ki oko oun foju kan omo e tori
pe won jo bii ni.
Oloye
Akande ni awon mejeeji ni won letoo lati gbo bukata lori omo naa nitori ojo
iwaju, ati pe ojo iwaju omo naa lo se pataki, nitori e ni won ko se gbodo je ki
omodun marun naa jinna sawon mejeeji. Bee ni won ro iyawo pe ko seto ona ti
Olayinka yoo fi maa ri omo e lasiko to ba wuu.
No comments:
Post a Comment