IDIBO AARE: Segun Sowunmi Di Agbenuso F'Atiku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 25, 2018

IDIBO AARE: Segun Sowunmi Di Agbenuso F'Atiku

Igbakeji Aare teleri lorileede Naijiria, Jenera Atiku Abubakar ti yan gbajumo oloselu nni, Ogbeni Segun Showunmi gege bi agbenuso fun eto ipolongo idibo Aare todun 2019 to n bo lona yii.


Segun Showunmi to ti figba kan ri je oludamonran pataki ati igbakeji akowe iroyin fun Gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel ni won kede e sita lai pe yi pe oun ni agbenuso fun eto ipolongo idibo to n bo lona.

Fawon to ba mo okunrin oloselu naa to filuu Abeokuta sebugbe daadaa, won yoo mo pe ko sipo yi won yan an sii ti kii se daadaa nibe, paapaa bo tun se je okan pataki lakoko ipolongo idibo odun 2015, iyen ti Goodluck/Sambo.

AWIKONKO gbo pe lesekese ti won ti yan Showunmi sipo naa ni won loo ti bere ise, ti won si tun ti si awon ibi ti won ti le ba a soro lori ero ayelujara, ti Twitter, Facebook ati Instagram.

Twitter: @SpokesmanAtiku
Facebook: @SpokesmanAtiku
Instagram: @SpokesmanAtiku

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI