Gbogbo awon to wa ni kootu koko-koko to fikale sagbegbe Ake
niluu Abeokuta ni bu serin lojo Tusde ose to koja yi nigba ti Baale ile kan,
Ogbeni Ibrahim Ayelotan yi ohun e pada pe oun ti gba pe oun loun lawon omo meji
tiyawo oun, Aishat Ayelotan bi.
Be o ba gbagbe, lose to koja la muu wa fun un yin labala yi pe
Baale ile n fewon sere, nitori to so pe omo ale lawon omo meji tiyawo oun,
Aishat bi foun, ati pe alagbere paraku ni.
Bo tile je pe a se asise rampe nipa ti ojo ta a gbe jade latari
(mistype) to sele, ti a si bebe fun asise naa pe ki e ma binu.
Aishat to gbe ejo lo sile ejo so pe oro naa ko tii pari nitori
pe latigba tawon ti kuro ni kootu ni Ibrahim ko ti beere awon omo naa, ti ko si
pe oun lati beere alaafia awon.
Ibrahim ninu oro e pe "Mo ti gba pe emi ni mo lawon omo
naa. Looto ni mi o beere won, idi si ni pe mi o fe pe lori aago, mi o si fe e
lo sodo e. Mi o fe mo, e je ko maa lo. Oro mi ko ju bee lo Oluwa mi."
Aare ile ejo, Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Onarebu
Arabinrin Majekodunmi H. I ni kii se pe lati tu won ka lo je isoro fawon,
sugbon omo gangan lo se pataki sijoba, eyi to maa n fa lati maa gbawon to ba fe
e ko ara won sile lati pada lo sile loo tun oro won gbe yewo boya atunse tun le
wa.
Oloye Akande ni bi ko ba si atunse, awon yoo tu won ka, tawon yoo
si gbe omo fun eni to ba kun oju osuwon lati toju omo. O wa sun ejo naa siwaju
di ojo kesan an, osu to n bo.
No comments:
Post a Comment