Eyi Ni Bi Won Se Le Awon Omo Orileede Naijiria Kuro Niluu Oyinbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 20, 2018

Eyi Ni Bi Won Se Le Awon Omo Orileede Naijiria Kuro Niluu Oyinbo

Ko din ni merinlelogbon (34) awon omo orileede Naijiria ti won le danu kuro niluu Oyinbo, iyen United Kingdom latari awon esun odaran ti won fi kan won.


Ni nnkan bi aago meji aabo osan onii, Wesde la gbo pe won fi baaluu (aeroplane) to n ko eru, iyen Cargo ti ileese Omni Air International pelu nomba idanimo W342AX ko won de si papa ofurufu Murtala to wa n'Ikeja ipinle Eko.

Okunrin mejilelogbon (32) ati obinrin meji pere la gbo pe awon eeyan naa ti won so pe o ti pe ti won ti n wa won, ati pe ayederu iwe igbeluu lopo won n lo lohun, leyi to lodi sofin won.

Nigba to n fidi isele naa mule nirole onii (Wesde), agbenuso awon olopaa ti papa ofurufu tiluu Eko, Ogbeni Joseph Alani so pe marundinlogbon (25) ninu awon ti won le pada ni won fesun odaran orisirisi kan nigba tawon to ku tapa si ofin to nii se pelu igbeluu, iyen immigration.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI