EYI NI BI IDILE KAN SE PARUN SINU ILE TUNTUN NI SAGAMU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 9, 2018

EYI NI BI IDILE KAN SE PARUN SINU ILE TUNTUN NI SAGAMU

Bo tile je pe titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan lawon dokita osibitu OOUTH to wa niluu Sagamu atwon olopaa ipinle Ogun ko tii le fidi iru iku to pa odiidi idile kan run un loru ojo Tusde mojumo Wesde ose to koja lele, sibe kayeefi niku awon eeyan naa si n je fawon araalu, paapaa awon olugbe Sagamu ti won gbo nipa iroyin iku naa.




Ko si nnkan to je koro iku molebi naa maa ya awon eeyan lenu bi ko se bo se je pe oorun akoko ti won maa koko sun ninu ile ti won sese ko niku wole to won, to si pa gbogbo run.

Baale ile, Ogbeni Egwuo Ikechukwu ti won nise Plumber lo n se; iyawo e, Arabinrin Chinyere Egwuo, atawon omo won, Goodluck Egwuo; Destiny Egwuo ti won lomo odun meji ni pelu aburo Chinyere ta ako moruko e dasiko yi, ti won loun naa mu omo e, Soda dani la gbo pe won ku sinu ile tuntun naa.

Adugbo Bashorun Adebisi Adesanya to wa lopopona Ayepe niluu Sagamu nisele aburu naa ti sele. Ogbeni Egwuo Ikechukwu tawon eeyan tun n pe ni Water, eni ti won lomo ipinleImo la gbo pe o sese koi le naa, leyin to ti lo opolopo odun lati fi ya ile gbe.

Ojo Wesde ose to koja yi la gbo pe Ikechukwu palemo eru e kuro nile to ya gbe pelu awon ebi lo sinu ile tuntun naa, tawon eeyan si n ba won yo ayo pea won naa deni to n nile lori lai mo pe ile naa ni yoo ran won lo sorun aremabo.

Bo tile je pe ko seni to koko mo nnkan to sele laaro ojo Tosde afigba tawon omose Water de lati mo nnkan to n sele, ki won too mo pe Water atawon ebi e ti ku. Ohun ta a gbo ni pe awon omose Water ni won ko tete rii ko yoju si soobu, ti won ni won pe e lori foonu, ti ko gbe e, bee la gbo pe won pe iyawo Water, iyen Chinyere lori foonu, toun naa ko lati gbe.

A gbo pe iru e ko sele ri, lo mu kawon omose Water gba ile tuntun ti won kolo naa lo lati lo mo nnkan to n sele, igba ti won maa debe, se ni won ba kokoro agadagodo lenu ilekun won, eyi lo tun mu ki won pe won lori foonu, ti won si n gbohun bi foonu na ninu ile.

Idi niyii ta a gbo pea won omose Water fi yoju loju ferese, ti won sir ii pe gbogbo awon to wa ninu ile naa ti ku, ko too di pe won pariwo sita fawon araadugbo lati mo nnkan to n sele, lesekese la gbo pe won ja kokoro naa, ti won si wa ona wonu ile.

Bi iroyin naa se jade sita lo mu ki AWIKONKO sare lo sibe lati loo fidi isele naa mule, ohun tawon kan an n so ni pe awon kan ni won waa fi kemika (chemical) tawon eeyan ko gbodo fa simu pa won sinu ile, ti won sit un tilekun mo won ki won maa ri aaye jade sita lati sa kuro ninu ile.

Lara awon to tun b’AWIKONKO soro tun je ko ye wa pe iku awon eeyan naa kii soju lasan, o lowo aye ninu, ati pe nigba tawon maa de ile naa, se ni gbogbo ayika ile naa n run kemika, to si tun je pe gbogbo awon to wonu ile naa lati gbe oku won jade ni won fi aso bo imu won, nitori oorun kemika naa lagbara pupo.

Okunrin kan to pe oruko ara e ni Femi, eni to tun je olokada so pe oun si ri Water atiyawo e nirole ojo ti won ko de ile, tawon si n kii ku oriire, bee lo so pe oun tun ba a dapara. Femi ni afi bi eni pe oun ko gbo pe eeyan ku ri, nitori pe iyalenu niku naa je foun pe eni toun ati e si jo soro lana.

A dele tuntun naa, agadagodo meji ni won fi tilekun ile naa pa. Koda, se ni won tun ti ile to wa legbe e pa, ko seni kenikeni nibe. Tanki omi kan wa nita ile oloogbe Water, digbi ni omi kun inu e, to si n jo danu lai ri eni pon on.

Bakan naa lara awon to n gbe adugbo naa to tun b’AWIKONKO soro je ko ye wa pe eeyan to lawo ni Water nitori pe bawon eeyan ba ti ba a darapa, se lo maa kawo e mejeeji soke, bo ba si se n ka sile, inu apo e ni yoo mu lo, ti yoo si fun eeyan naa lowo.

Opo awon eeyan tun n so pe awon ko wa a le so nnkan to de ija sile laarin Water atawon to seku pa oun ati molebi e mo inu ile, nitori pe erin lo maa n rin lopo igba, kii binu, bee ni kii baayan yan odi.

Won ni aaye opo kan soso ti Olorun fi sile fun idile Water ni bo se je pe omo e meji pere ninu omo ti Water atiyawo e bi lo ba iku naa lo, nitori pe awon yen ko si lodo won lasiko ti won ko lo sile tuntun naa

Nigba ta a de osibitu Olabisi Onabanjo naa to wa leyin aafin Akarile tile Remo, iyalenu lo je pe inu ogba osibitu naa ko gbero, ko too je pe nigba to ya, se lawon sikioriti tilekun enu ona abawole pe enikeni ko gbodo wole mo.

Okan lara awon osise mosuari osibitu naa to b’AWIKONKO soro, Ogbeni Akingbe Raphel, bo tile je pe ko gba lati wonu mosusari naa ya foto, sibe, o salaye pe awon ko ti i le so pato ohun to pa won, afi tawon ba sayewo ti won maa n se lara oku, iyen autopsy lawon yoo too le fidi ohun tawon eeyan n so mule boya bee ni, tabi bee ko.

Ogbeni Akingbe gan an lo je ko ye wa pe omo ipinle Imo ni oloogbe yii atiyawo e, o ni eni odun merinlelogoji ni Chinyere to je iyawo Water, awon to gbe won wa ko le so iye odun oko. Omo odun meji lo pe Destiny ti Chinyere n to lowo, obinrin ni, egbon re ni Goodluck toun je okunrin.

O ni molebi Chinyere ni obinrin to ba won ko wole tuntun naa, omokunrin ti won jo wa loruko tie n je Soda, omo odun metadinlogun si ni. Awon mefeefa ni won pade iku ojiji kile too mo, ti won gbe won jade ninu ile ti won fese ara won rin wo nirole ojo ti won ko de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI