Amosun lo soro yi lai pe yi nigba to n bawon omo leyin Anobi soro ni Yidi Lantoro to wa niluu Abeokuta, nibi to ti loo kirun fun ti ipari aawe naa.
O so pe kii se awon Musulumi nikan ni won n se ayeye odun Itunu Aawe, pelu awon elesin Kirisiteeni lawon jo n se e, nitori pe awon jo kopa ninu aawe naa ni.
Nigba to n ki awon omo ipinle Ogun jakejado fun ti ponponsinsin odun naa, Gomina Amosun ninu oro e so pe "Mo ki gbogbo omo ipinle Ogun pe a ku odun, a si ku iyedun, emi wa a si maa ri odun.
"Adura ta a gba ninu odun yi, Oluwa a mu lo sile ase. Awa ta a se todun yi naa la tun maa se eyi to n bo. Mo fe e ba gbogbo omo ipinle Ogun yo, mo fe e ki gbogbo Musulumi ati Kirisiteeni kaakiri. Eleyi je nipa ti ipinle Ogun to je wa logun, bo ya o je Musulumi tabi Kirisiteeni.
"A ti mo pe ko sigba ta a ba n sajoyo bayii, gbogbo wa patapata la je okan soso. Mo si gbadura pe bi a se n sajoyo ayeye odun Ramadaani todun 2018 yi, inu owo, ayo, alaafia ati aiku baale oro la ti maa se.
"E je ka yago fun ese patapata fun ese. Gbogbo awon nnkan ti a o se, ta a yago fun, gbogbo awon nnkan ti a sa fun ninu osun Ramadaani, e ma je ka pada sinu e mo. Bi a ba n fe ki Olorun tubo maa tesiwaju lati maa dahun adura wa, a fi ki a yago fun ese.
"E je ka tubo tesiwaju lati maa nife ara wa, ki a maa fi ife ba ara wa lo po. E je ki a si ko ara wa nijanu ninu ohun gbogbo ti a baa n se."
Nigba toun naa n soro, Alaaji Liadi Orunsolu to je Imaamu agba nipinle Ogun so pe asiko yi gan an ni a gbodo mo riri adura Olohun, ki a si maa tesiwaju lati maa sin Olohun nigba gbogbo.
Imaamu agba naa gbosuba kare fun Aare Muhammadu Buhari pelu bo se bu ola fun Oloogbe Oloye MKO Abiola pelu ami eye idalola to fun un gege bi Aare teleri lorileede Naijiria.
No comments:
Post a Comment