Asiri Pasito to fe e fomo e soogun owo l'Owode-Yewa ti tu o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 25, 2018

Asiri Pasito to fe e fomo e soogun owo l'Owode-Yewa ti tu o

Awon ti won so pe 'ajumobi ko kan taanu, eni abinibi gan an lo n seni' won ko paro rara nitori pe oro naa se deede bi Pasito soosi kerebu kan ti won poruko e David Akinlalu se fe e fomo e to bi ninu soogun owo latari bo se so pe ise ati osi to n ba oun finra loun fe e gbon danu, koun si di olowo yanturu laarin ilu.

Gege ba a se gbo, bo tile je pe kii se akoko re e ti David tojo ori e ko tii ju odun mejilaadota lo fi omo e soogun owo, nitori ta a gbo pe odun 2013 lo koko lo omo e kan lati fi soogun owo, sugbon ti owo naa ko de, to si je pe se ni won fi emi omo naa sofo danu lasan ni.

Won ni latigba naa ni David to n gbe l’Owode Yewa ti n wa ona min in ti yoo tun dogbon soro ara e, ti ko nii lo eeyan mo, to si je pe orisirisi nnkan lo ti se lati ri owo, sugbon to je pe pabo lo n ja si fun un.

Idi ni yii ti won loo tun fi loo foro e to awon Pasito meta min in leti, ti won lawon naa gbona ninu ka fi eeyan setutu owo, ati oogun aworo sinu soosi, iyen awon to pe ni pasito Idowu Alabi, Friday Salako ati Nesto Fashihun.

Awon yen ni won so fun un pe ko loo wa omo ti won yoo ba a lo lati fi setutu owo fun un, toun naa si pinu lati fi omo e Peter Akinlalu to je omodun metala sile fun etutu owo owo.

Kani David mo pe asiri oun tit u sawon olopaa lowo ni, o see se ko ma ti ronu loo fa omo naa le awon to fe e baa setutu owo naa lowo, nitori ta a gbo pe oju ona nibi to ti n mu omo naa lo lowo tit e e lojo Wesde to lo lohun, iyen ojo ketala osu yii.

Oun gan an lo mu awon olopaa lo sabe biriiji to wa ni Sango nibi tawon pasito meta ti won ni orileede Benin ni won ti wa ti n duro de e lati loo fomo naa setutu owo fun un.

Nigba to n soro, David so pe “Awon pasito naa seleri fun mi pe ona tawon yoo gbe oogun owo naa gba fun mi maa ya mi lenu nitori pe eru gan an a ba mi bi owo mi ba de, temi naa yoo si maa figagbaga pelu awon olowo laarin ilu.

“Mi o mo pe awon olopaa n so mi, Owode Yewa ni won ti mu mi. Emi ni mo mu won lo si abe biriiji Sango, nibi tawon meta yen ti n duro de mi ki n le mu Peter ta a fee fi sowo le won lowo, bi won se mu awon naa niyen’’

Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti so pe o see se ko je pe ose yi ni won yoo foju awon mereerin bale ejo nitori pe iwa odaran to tapa sofin ni won hu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI