Adije sipo gomina ipinle Ogun labe egbe oselu ADC lodun 2019, Omoba Gboyega Nasir Isiaka,GNI ti so pe kijoba apapo yo oro oselu kuro ninu ipaniyan to n fojoojumo sele lorileede Naijiria, paapaa eyi to n sele ni guusu orileede yi, to fi mo eyi to sese sele lai pe yi nipinle Plateau.
GNI lo soro naa lai pe lati enu oludamonran pataki lori oro iroyin, Ogbeni Wale Junaid pe asiko re e fun ijoba apapo orileede yi lati gbajumo eto aabo emi ati dukia awon araalu, ki won si tete je ko je won logun.
Be o ba gbagbe, lojo Sande to koja yi lawon agbebon kan ti won pe ni Fulani daran-daran ya wo ilu Jos, ti won si pa eeyan ti ko din ni ogorun kan, to fi mo awon omo kekeeke ni won ran lo sorun aremabo losan gangan.
GNI so pe kii se asiko re e tijoba apapo yoo maa ti oro oselu bo wahala ati ipaniyan to n lo kaakiri orileede yi, eyi to n mu kawon eeyan maa wa ibi ti won yoo fori won pamo si fun alaafia, di po bee, ki won wa iyanju ti yoo dekun gbogbo wahala naa patapata.
Bee lo so pe ki won wa ona bi won yoo se mu awon to wa nidi isele buruku naa, ti won yoo si foju won bale ejo lati jiya ese won.
O ni eto aabo ilu wa lowo ijoba, paapaa Aare orileede yi lai fi toro eleyameya se. Ati pe iru awon isele bayii ti fi han daju pe egbe oselu APC ki kuna patapata, won si ti ja awon araalu kule.
Bakan naa latari oro ti okunrin kan ti won poruko e ni Miyetti Allah fi sita kii se pe won deede pa awon eeyan naa, sugbon esan maluu ti to le ni oodunrun (300) ti won ji ko lo lawon eeyan naa gba pada lati femi awon araalu sofo danu.
GNI so bu enu ate lu oro naa pe ko bojumu lati fi emi awon araalu dupo eranko ti won ni won ji ko lo.
Nigba to n kadi oro e, Isiaka fi awon omo ipinle Ogun lokan bale pe aabo to pe ye yoo wa fun won bi won ba dibo foun lodun 2019 nitori pe gbogbo awon ileese eleto aabo kaakiri loun yoo ba ni adehun, ti won yoo si sise papo.
No comments:
Post a Comment