Arabanbi Soko Oro S'egbe Oselu APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 26, 2018

Arabanbi Soko Oro S'egbe Oselu APC

Alaga egbe oselu Labour nipinle Ogun, Komureedi Oluwafemi Abayomi Arabambi ti bu enu ate lu bi egbe oselu APC lorileede Naijiria se yi akomona won kuro ni Senji (Change) si itesiwaju (Progress).


Komureedi Arabambi lo bu enu ate lu iwa naa lai pe yi ninu atejise to fi ranse sori WhatsApp pe egbe ti ko ba le di akomona won mu fodun merin, ko ye kawon eeyan tele won rara.

O ni kawon eeyan fibo le won danu basiko idibo ba de lodun 2019 nitori pe won ti dale awon araalu, won ko si se nnkan tawon araalu n fe fun won.

Arabambi tenu mon on pe bi awon omo Naijiria ko ba tete le egbe oselu APC danu lodun to n bo, o see se ki won yi oruko Naijiria pada bi won ba dibo yan won pada sipo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI