Ajimobi Ti Oja Bodija Pa N'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 28, 2018

Ajimobi Ti Oja Bodija Pa N'Ibadan

Gomina ipinle Oyo, Abiola Ajimobi yi pase pe ki awon alabojuto oja Bodija to wa niluu Ibadan ti oja naa pa ni kiakia ko too pe ju lati daabo bo emi ati dukia awon araalu.


Ase yi waye leyin wahala kan ti won loo be sile laaro oni, to mu ki awon eeyan bere sii fori-gbari lati sa asala fun emi ara won.

Gege bi a se gbo, won ni ijoba ipinle Oyo pase pe ki awon eleran to n pa eran ni oja Bodija to gbajumo daadaa naa kuro lo sibo min in, eyi ti won ni ko te awon eeyan naa lorun, tijoba si loo wo soobu won lopin ose to koja yi.

Ojo Tusde la gbo pe awon oloye egbe eleran to fi mo awon omo egbe won ni won loo si ofiisi Gomina Ajimobi lati loo fi ehonu won han pe ki won ma se le awon kuro nibe, sugbon ta a gbo pe ijoba ko gba fun won.

Eyi gan an la gbo pe o fa a tawon eleran fi so oro naa di isu ata yan-an-yan-an, ti won si bere sii yinbon lemo-lemo, eyi ti won loo ko iberubojo sokan awon to wa layika ati agbegbe oja naa.

AWIKONKO gbo pe nnkan to fa a ti won loro naa fi yiwo ni bawon eleran naa se fesun kan awon oloye oja naa pe won ti gba owo abetele lowo ijoba, eyi ti ko je ki won le gbe leyin won lati ba ijoba soro pe ki won ma le won kuro nibe.

Alaga ijoba ibile idagbasoke Latoosa, Ogbeni Adekunle Oladeji ni won loo lewaju awon to lo ti oja naa pa.

Ohun ti Ogbeni Oladeji so ni pe lati le je ki wahala to be sile naa lo sile lo mu ki Gomina Ajimobi pase pe kawon tete loo ti oja naa pa.

Bee lo so pe awon osise eleto aabo ti wa kaakiri ayika ati agbegbe oja naa lati ma je ki wahala min in tun be sile. O wa ro awon araalu lati ma se de agbegbe naa titi digba ti won yoo pase pe kawon eeyan maa rin koja lagbegbe naa.

O ni eni tawon eleto aabo to wa nibe ba rowo to yoo fenu fera bi abebe nitori pe se ni won yoo fesun kan gege okan lara awon to wa a tu oja naa ka.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI