A SI N FE IRANLOWO AWON ARAALU - ALAAJI UMAR - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 26, 2018

A SI N FE IRANLOWO AWON ARAALU - ALAAJI UMAR

Alaga egbe awon ajo alailobii lorileede Naijiria, iyen Orphans and Disadvantaged Persons Care, eka tipinle Eko, Alaaji Umar Lawal Atanna ti rawo ebe sawon omo orileede yi pe ki won dide iranlowo fun ajo won, lati le je ki ipinu won lati di ise ati osi ku lawujo.  Ninu iforowero ti Alaaji Umar b'AWIKONKO se niluu Eko lo ti salaye kule-kule nipa ajo naa atawon aseyori ti won ti se nipa sise iranlowo fawon eeyan, paapaa awon omo alailobii. E kaa bi iforowero naa se lo.

ORUKO YIN ATI BI E SE JE?
Oruko mi ni Alaaji Umar Lawal Atanna, emi ni alaga egbe awon oludasile ile awon omo alailobii ati ajo oniranwo fawon eeyan lorileede Naijiria, iyen Orphans and Disadvantaged Persons Care labe ajo Jama'atu Izalatil-Bid'a Wa'lqamatis Sunnah (The Islamic Organization For Eradicating Bid'ah And Establishing Sunnah), eka tipinle Eko.

KI LO BI AJO YI?
Idi ta a fi da ajo yi sile ni pe mo ti n ni lokan pelu ase Olorun Allah alagbara, to da ohun gbogbo, ohun naa lo n pese fawon to baa n beere nnkan ti won n fe. Ajo yi wa kaakiri orileede Naijiria, a si ni olu-ileese wa niluu Abuja, a tun ni eka si ipinle Kaduna. Igba ta a da sile la woo pe ipinle kookan gbodo ni alaga won. A ni eka sawon ipinle bii Kano, Kaduna, Sokoto, Abuja, Eko atawon ipinle min in. Odun 2016 la da a sile, igba ta a si da a sile, emi ni alaga igbimo amuseya ta a yan nigba yen labe ijoba ibile Agege. Igba ti won ri ise ti mo se laarin odun kan, ni won gbe mi kuro nijoba ibile, ti won si gbe mi si ipele tipinle. Karakata ni mo n se tele ki a to o bere ajo yi, ise awon to n yi owo pada, iyen Bureau-De-Change.

AWON ASEYORI YIN?
Aseyori po repete nigba ti a ti bere, paapaa nigba ti mo bere pelu ijoba ibile, tawon to wa nipinle si ri ise takuntakun ti mo se nibe, idi ni yii ti won fi so mi di alaga ipinle. Odun keji ti wom tun yan mi gege bi alaga, asiko aawe Ramadaani to sese pari yi ni won yan mi. Ojo kejilelogun ni won mu iwe wa pe.awon fe e ki n di alaga ijoba ibile yen, nigba ti won mu iwe yen wa, mo so fun won pe ibeere mesan an ni maa beere lowo won ki n to so fun pe mo ti gbo. Awon ibeere naa ni pe: ki lo de ti won fi yan mi lakoko, won ni mo n je kawon eeyan mi ni Mosalasi kaakiri mo bo se n lo; eleekeji, awon meloo ni won fe ki n saanu fun lasiko aawe Ramadaani, won ni 461; mo tun beere pe igba wo ni won bere ajo yi, won ni odun to koja; mo bee pe awon meloo ni won ti se, won ni ogorun le ni marun (105); mo tun beere pe eelo ni won ni ninu akanti won, won ni egberun marundinlogorun (95,000) naira, nibe ni mo ti rerin pe bawo ni mo se fee se egberun marundinlogorun naira ti won ni ki n fi bo awon 461, awon naa dahun pe awon mo pe mo le se e. Mo tun wa beere lowo won pe se won ni akanti to je pe ti n ba ni kawon eeyan maa da owo si fun won, won si lawon ni. Bee ni mo tun tete beere pe won ni ofin ati ilana to de won, ki n maa baa ko owo won je, won lawon ni, ati pe ko odiwon iye owo ti mo le na, nnkan tawon n fe ni aseyori.

Leyin yen ni mo wa a bere sii lo kaakiri awon Mosalasi, ibi ti won ti n gbadura, ibi tawon to n paaro owo wa, Airik Airport, awon ile eleran, soobu itaja ati bee bee lo lati lo maa ba won soro. Ko je iyalenu pe laarin ojo mejo yen, mo ri owo to too toju awon 461 yen nitori pe awon araalu da sii. Igba yi ni won wa a gbe mi sipo ipinle lodun 2017, awon 16300 ni mo ran lowo nitori pe awon eeyan n wa lati Mile 12, Apapa, Idi Araba, Badagry.

Nigba yen, nigba to di pe telo to fe e bawon omo naa ran aso de, la sakiyesi pe pupo ninu awon omo naa ni ara won ko ya, mo wa a se foomu kan lati mo oruko awon omo naa ati iru iya to n je omo kookan. Bi mo se n soro yi, mi o le ka iye awon omo ti o wa ni akata wa, won ti le legberun marun nitori pe a awon eka ti a ni, ni won ni igbimo.

A ko fi oro eleyameya se iranlowo yi nitori pe bi e ba wo awon iwe iroyin to n jade kaakiri lori oro iranlowo yi, gege bi esin Islam, alailobii ko loriluko meji, yala Kirisiteeni, Yoruba, Hausa, Ibo, Musulumi, Fulani, ati beebeelo, to ba saa ti je lati omodun merinla wa si isale. Ko nni se pelu eleyameya, mo si tun fe je ki e mo pe laarin awon egberun marun un yi, ko din ni egberun kan ninu won ti won je omo Yoruba.

ANFAANI TI YIN
Anfaani temi bi mo se n kaakiri yi ni pe ki n gbo si Olorun Allah to da mi lenu. Mo feran lati maa saanu awon alailobii, o si ti mo mi lara, nitori pe bi a ba n toju won, ile aye maa dara. Ki ni anfaani pe omo mi won aso tuntun, ti omo elomin in ko le wo aso tuntun. Eleekeji ni pe bi omo ba ji laaro kutu ti ko ri eni to maa toju e, iru omo be e maa se isekuse, ibe la si ti maa ri awon omo to maa lo maa mu igbo, ti won a si tun maa jale. Aso odun la fi bere fun won lodun yi, ka si le mo iye won. Eleekeji ni pe a gbe awon Dokita wa lati wa maa se ayewo fun won.

Awon egberun meji ataabo la ti sayewo fun, lara won la si rii pe won ni aisan iba, taifoodu, atawon aarun min in bii eela. Won n fun won loogun, abere, bee ni won tun n fun won lawon nnkan to le je ki won wa ni ilera pipe. A n se irun fawon obinrin, a n ge irun ori awon okunrin to ba kun, bee la tun n ra bata fun won.

IPINU YIN FUN OSELU?
Emi kii se oloselu, mi o si gbadura pe ki n di oloselu, ti m ba fe e se oselu, mi o le se oselu niluu Eko, se ni maa pada lo siluu Kano ti mo ti wa lati loo se oselu mi nibe. Ti m ba si fe e se oselu nibi, mo gbodo gbo ede Yoruba, eyi ti o gbo rara.

IPINU YIN FUN OJO IWAJU?
Ipinu mi fun ojo iwaju ni pe mo fe e maa ran awon omo yii lo sileewe, ki won si maa kawe kekoo-gboye. Lati ko ileewosan fun itoju to pe ye fawon omo yi, lati ko ile fawon omo yi, lati ko ileese to se e wo loju ati lati ra moto to le maa ko awon omo naa kaakiri. Bi e ba wo orileede yi, e maa rii pe bi omo kan ba padanu baba e, o maa n soro fawon iya lati toju iru awon omo bee, paapaa awon ti won ko ba nise lowo. Bi baba min in to je olowo ba ku, won maa n pin ogun fawon omo, bi akuse ba ku, iya lo maa gbo bukata. Bi a ba so pe a fee yi orileede yi pada, a o le fi sile fun ijoba nikan lati se. Onikaluku wa la nise lati se, ki a si pese fawon ti ko ni, ki orileede yi le dara. A si n fe iranlowo awon araalu lati gbaruku ti wa, ki edinku le de ba ise ati osi lorileede yi.

ABAMO?
Mi o tii kabamo, mi o si nii kabamo. Igba kan n bo temi naa si maa so pe mo fe e fi sile, igba ti n ba si so eyi, enikan naa wa to je pe to ba gbo, inu e ko nii dun rara. Ipa rere ni mo fe e fi sile bo tile je pe awon kan n se ilara pe ki lo de ti ko je awon, to je emi ni. Awon kan si wa to je pe oju opopona ni won a lo lati lo maa so nnkan to wun won. Mo nigbagbo ninu awon ti won n ba mi sise po, bi mo se n ba a yin soro yi, ko din ni ogoji lawon to n ba mi sise. Onikaluku won lo wa ni eka ti won ta a ya soto.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI