WON NI IJA NLA BE SILE LAARIN KASNATY ATI ALAYO SINGER - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 28, 2018

WON NI IJA NLA BE SILE LAARIN KASNATY ATI ALAYO SINGER

Bi iroyin to n lo kaakiri igboro bayii ba fi le je otito, a je pe oro naa ti wa a di 'a ti t'oje bo oloosa lowo, o wa ku baba nla baba eni ti yoo bo' laarin gbajumo sorosoro to f'iluu Abeokuta se'bugbe, iyen Kolawole Atanda Adejojo tawon eeyan tun mo si Kasnaty ati ilu mooka olorin Juju nni, Michael Ayoola Akinola topo eeyan mo si Alayo Melody Singer.


Gege b'AWIKONKO se gbo, oro naa ti won lo ti n lo labele laarin awon mejeeji ti aye n gba ti won nidi ise ti won yan laayo, tawon mejeeji si n se e ni oku oru la gbo pe o ti wa a ja sita gbangba bayii.

Aroko la gbo pe awon mejeeji fi n ranse sira won bayii, ti won si n gbena woju ara won.

Ohun ta a gbo ni pe oro ta lo dagba ju ni won loo da wahala naa sile, eyi ti won loo mu ki Alayo fi korin pe 'Se o mo age mi ni?'.

A gbo pe bi orin naa se ta si Kasnaty leti, loun naa ba gba ori redio lo ninu okan lara awon eto to maa n se nileese redio OGBC, toun naa si loo bere sii fo igba ayangan nibe pe ojo ori ko je nnkankan, ati pe eeyan gbodo gba fun eni to juu lo ni, nitori pe ko seni to wa nibe nigba ti won jo bi ara won.

Orin ti won ni Alayo ko yi la gbo pe o fee se ikojade nirole onii niluu Abeokuta, to si ti ranse pe opo awon eeyan lati wa a ba a gbe jade sita.

Ekunrere iroyin naa n bo lai pe. E ku oju lona.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI