Won l'Oba Adewale Olaifa tiluu Ilase ti gbabodi siluu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 14, 2018

Won l'Oba Adewale Olaifa tiluu Ilase ti gbabodi siluu


...Nitori ayederu wolii to fipa f'omodun mewaa loyun

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lopo awon ara ilu Ilase nitosi Idiroko, ipinle Ogun si fi n binu si Kabiyesi won, Alase tiluu Ilase, Oba John Adewale Olaifa, ti won si n so pe kijoba ipinle Ogun gba awon latari bi won loo se fi ayederu wolii kan to fipa f’omodun mewaa kan loyun sile pe ko maa lo pelu ogbon wi pe oun ti le e kuro niluu.

Ayederu Wolii
Gege b’AWIKONKO se gbo, ayederu wolii ti won pe oruko e ni Michael, to je omo bibi ilu Ondo la gbo pe o ji omodun mewaa kan ta a foruko bo lasiri gbe pamo sile e lati osu keji odun yi, to si n fojoojumo ko ibasun fun, titi to fi loyun, ko da tawon kan so pe oogun lo fi ba omo naa soro, to ra a iye e patapata.

A gbo pe gbogbo igba ti omo yi fi wa lodo Michael ni ko le soro sita fawon to wa nitosi, ko da ti won ni pelu bo se maa n ri awon egtbon e to ba n koja lo sileewe, ko le lanu lati pe won.

Ohun ta a tun gbo nipe, se lawon obi omo yi ko foro omo ti won n wa naa to awon olopaa leti, to je pe abele ni won ti n wa peluu oogun atawon nnkan min in, gege baa se gbo.

Nigba tasiri maa tu, se ni won ni Michael so pe ki omo naa maa lo sile lati loo farahan awon obi e, ko si pada wa lojo keji pelu aso ti won loo ra fun un, bawon obi omo naa se foju kan omo won, ni won bere sii beere orisirisi ibeere lowo e nipa ibi to lo, to si jewo pe odo wolii loun wa.

Omo naa
Lesekese la gbo pe won ti pariwo sita, ti won si gba ile Oba Adewale Olaifa lo lati loo fejo sun un, ti won ni Kabiyesi pase pe kawon oloye pelu awon odo kan loo muu. ojo keji la gbo pe ri pada ri Michael, ti won si muu lo si aafin nibi ti won ti foju e han fawon araalu.

Ase ti won ni Alase tiluu Ilase naa pa ni pe ki won fun ayederu wolii na legba, ki won si lee kuro niluu lati ma ba ilu won je, sugbon ti won ni ko dun mo awon kan ninu, nitori pe se lo dabi eni pe Kabiyesi naa mo nipa iwa ti Michael hu.

Won ni se lo ye ki Oba Olaifa fa Micahel le awon olopaa lowo lati foju e bale ejo, ko si le sewon latari bo se ji omolomo gbe, to n fojoojumo ko ibasun fun titi to fi loyun mo on lowo.

Okan lara won to b’AWIKONKO soro to ni ka foruko boun lasiri so pe “Lati osu keji odun yi la ti n wa omo yen, awon obi e n wa labele, won ko pariwo sita nitori pe bi won ba pariwo sita, o see se ko gbe omo naa lo si Ondo to ti wa lati lo fi soogun owo.

Lasiko ti won n luu
“Igba to di ojo Sande ojo kokandinlogbon osu to koja, la deede ri omo naa to de pelu bagi aso. Nigba ta a bere sii beere oro lowo e, lo je ka mo pe Wolii lo mo oun sodo. omo naa so pe oun maa n ri awon egbon oun ti won ba n koja, sugbon oun ko le soro lati pe won, ati pe wolii lo so pe koun maa lo sile, koun si pada wa.

“Ko sise wolii mo nitori pe igba kan wa to se asemase, tawon ijo sele ti wa a ba a pe ko yee ba oruko awon je, latigba naa ni soosi e ti daru, soosi e naa ko loruko, sugbon se lo n lo ori awon eeyan nigba yen. Ko se soosi mo bi mo se n baayin soro yi, isegun lo n se, to n pawoda. Ko seni to n lo soosi e mo, se lo n dagbe, nitori pe ko niyawo.

“To ba feyawo lonii, to ba fi maa to ose kan, iyawo yen maa ko kuro ni. Bi iyawo kan ba bimo fun un lonii, to ba maa fi to osu die, se niyawo naa maa fi si sile lo. Wolii ni mo mo si latigba ti mo ti mo, sugbon nigba to fi n sise wolii yen lawon eeyan ti maa n lo sise lodo e, to fi je pe nigba ti ko se wolii mo, awon min in si n lo sodo e pe ko bawon sise isegun.

“Kabiyesi lo so pe ki won lee kuro niluu pe ki won loo gbe orisa sile e. O see se ko wa niluu ko je pe se lo sapamo, sugbon a si n wa lati muu, ka le loo fa le awon olopaa lowo funra wa.”

Lati tan imole si oro naa, AWIKONKO teko leti lo siluu Ilase lati ba Kabiyesi atawon obi omo naa soro, sugbon o seni laanu pe nigba ta a de be, a ko ba Kabiyesi, Oba Adewale Olaifa nile, won ni Kabiyesi sese jade ni, olori e si ba wa pe e lori foonu, toun naa so pe looto ni, ati pe oun ko fe e soro mo lori e, nitori pe oun ti fa a le awon olopaa lowo.

Iyawo Kabiyesi naa to so pe ki olokada kan mu wa lo sile eni to sunmo awon obi omo naa, ki won si le mu wa de ile won, sugbon iyalenu lo je pe nigba to ku die ki obinrin naa mu wa de odo aburo iya omo yi, se ni iyawo Kabiyesi pe olokada naa lori foonu pe ko so fun eni to n mu wa lo pe ko gbodo mu wa lo mo, nitori pe awon ko fe ki oro naa jade sita, ti obinrin naa si yipada lesekese pe oun ko fe wahala fun ara oun.

Nigba ta a salaye fawon to gbe iroyin naa si wa leti, won je ko ye wa pe awon mo pe Kabiyesi naa ko ni fe e soro nitori pe ayederu wolii naa pelu awon to n sise isegun fun Oba Olaifa, ti ko si fe e ki asiri e tu sita, eyi to fe e se e ni oku oru.


Leyin ti won luu tan
Won ni iru iwa gan an ni Oba Olaifa hu nigba ti okan lara awon olopaa SARS ti won pe ni Lawal Wasiu yinbon pa Ogbeni Paul Hedowu siwaju aafin e lojo kerindinlogun osu kejo odun to koja, to si je pe gbogbo igbiyanju lo gba lati se oro naa loku oru, sugbon ti ko seni to mo ibi ti won fori ejo naa ti si.

Won lawon ko le gba ki Kabiyesi ti won niwa igberaga e ko je kawon araalu gba ti e wa a maa ba tawon eeyan pelu ipo ti won gbe e si, ti kii se titi lai.


Lati mo boya looto ni Kabiyesi fa Michael le awon olopaa lowo, agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n b’AWIKONKO soro so pe bo tile je pe oun ko tii gbo nipa isele naa, nitori pe ko seni to fi to olu ileese olopaa leti, sibe o bu enu ate lu iwa ti Oba Olaifa hu pe ko si kabiyesi to letoo lati se idajo lowo ara e fun afurasi odaran.

O ni iru Oba bee, a je pe o lebo leru ni, bee lo seleri pe oun yoo je ka mo leyin toun ba sewadi isele naa toun yoo si je ka mo boya looto ni tabi ko ri bee, subon ta a ko tii gbo esi titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI