Lojo Tosde to koja yi
ni Ogbeni Tobiloba Ipense to ni soosi Kerubu ati Serafu ti Holy Garden to wa ni
Papa/Ewekoro la gbo pe o foju bale ejo, pelu okan lara awon alabasisepo e
Oluwakemi Ishola.
Be o ba gbagbe,
Tobiloba Ipense ni pasito ti won so pe o seku pa Iyaale ile kan, Raliat Sanni
to ti bimo marun un, to si loo ri mole sinu soosi e lati fi se oogun aworo ni
nnkan bi osu meji seyin.
Gege ba a se gbo, esun
meta otooto ni won fi kan Tobiloba, lara awon esun naa ni pe esun apaaya, ati
gbigbe oku eeyan pamo ti won loo lodi si ofin orileede yi.
Bo tile je pe adajo
naa, Ogbeni S. M Banwo so pe ko si aaye lati gba beeli Tobiloba, sibe o gba pe
ki won gba beeli Oluwakemi ni milionu meji ataabo (2.5) naira pelu oniduro
meji.
Bee lo sun igbejo si
ojo ketadinlogbon osu keje odun yii.
No comments:
Post a Comment