Soosi ni Patrick dagbere, ki won too pa danu l’Odogbolu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 16, 2018

Soosi ni Patrick dagbere, ki won too pa danu l’Odogbolu

Kayeefi loro awon ore meji ti won ni won ko nise meji ti won n se ju ki won maa ji awon eeyan gbe, ki won si maa pa won ta fawon to n soogun owo si n je fawon araalu Odogbolu nipinle Ogun.

Yoruba bo, won ni ojo gbogbo ni t’ole, ojo kan soso bayii ni t’olohun, eyi gan an lo lo nibamu pelu b’owo awon eso fijilante, Vigilante Group of Nigeria (VGN) se te ore meji kan ti won pa gendekunrin kan ti won p’oruko e ni Patrick, eni ti won so pe soosi lo dagbere laaro ojo Tusde ana, sugbon to je pe owo won lo ko si.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni ni nnkan bi aago mefa aaro ni Patrick so fawon ebi e pe oun fe e lo si soosi, lati loo ro awon oko to kun sibe, koun le tete pada sile nitori ibi toun n lo.

Iyalenu lo je pe won alo Patrick ni won ri, won ko ri ipadabo e titi di nnkan bi aago meta osan, ko da a, ti won tun wa a lo si soosi naa, sugbon ti won ko rii. Eyi lo fa a ti won tun fi bere sii wa bi abere to jabo sinu agbami okun.

Nigba ti won ko ri Patrick, lo mu kawon ebi e loo foro naa to adari egbe VGN to wa ni Imodi, ijoba ibile Odogbolu leti ni nnkan bi aago marun un, irole, lesekese ni won ti gbera lati bere iwadii.

AWIKONKO gbo ko tii ju wakati meji tawon fijilante VGN yi bere ise iwadii won, kasiri odaran kan ti won pe ni Patrick Udoh fi tu si won lowo, nigba ti won ba apo saka kan lowo e, tie je yi gbogbo ara e. Eyi gan an ni won loo mu ifardani fawon eso VGN naa.

Ohun ta a gbo ni pe egbe soosi naa ni Patrick Udoh ti won loo seku pa Patrick n gbe. Won ni ibi to ti n duro de onibara e ti yoo wa a ra oku naa lowo ti te e, lesekese lo si ti pariwo sit ape ki won se oun jeje, ati pea won meji lawpon sise naa.

Oga awon VGN nipinle Ogun, Ogbeni Olanrewaju Nureni Adedoyin nigba to n b’AWIKONKO soro losan oni fi idunnu e han lori ona tawon omose e gba rowo to awon odaran naa.

Adedoyin to so pe ilu Abuja loun wa je ko ye wa idanilekoo oore-koore tawon n gbe kale fawon omo egbe won lo tun so eso rere naa. Bee lo rawo ebe sawon araalu pe ki won maa fi ohun gbogbo to ba niise pelu odaran to awon omo egbe won leti nitori pe awon gan an ni won sunmo awon araalu ju, ati pee mi ati dukia awon araalu lo je won logun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI