Ko seni to gbo bi gendekunrin eni odun
metalelogun (23), Gbenga Ogunsanya ti won tun n pe ni Spartacus se n ka
boroboro lojo Satide to koja lo lohun logba SARS to wa ni Magbon niluu
Abeokuta, ti ko nii mo pe ogbologbo odaran paraku ni, ko da, tawon to gbo bo se
n soro si n so pe a fi ki won da ejo iku fun un, pelu bo ti se gba opolopo emi
awon eeyan.
Ohun ta a gbo ni pe ojo kejila osu to koja yi
lowo olopaa SARS te Spartacus to je olori omo egbe okunkun ti Aye ladugbo Sabo
niluu Abeokuta lakoko to tun fe e pa okunrin kan ta a ko tii moruko e dasiko
yi.
A gbo pe lati osu kinni odun yi ni awon
olopaa ti n wa Spartacus leyin to da wahala nla sile nibi ayeye odun tuntun ti
Gomina Ibikunle Amosun maa n sagbateru e lojo kokanlelogbon osu kejila si ojo
kinni osu kinni odun tuntun.
Gendekunrin naa ta a gbo pe Oke-Bode lo n gbe
tele, sugbon iwa buruku owo e lo je ki won le e danu leyin ti won ni o loo fa
ijogbon ladugbo Ago-Oka, nibi ti won ti gun un loju, ko too dip e babalawo kan
ti won lo roo lagbara ti gbe e lo toju.
Oogun naa la gbo pe o n gun un, to si bere
sii paayan nipakupa, eyi gan an lo gun loo sibi ayeye odun naa lojo naa, to si
je bi gomina Amosun se kuro nibe lojo naa, lo bere ti e, to si se opo awon
eeyan nijamba.
Spartacus so pe idi toun fi ko oruko sorun ni
ti fiimu kan toun wo, to je pe eni to n je oruko naa kii gbo ebe nigba to ba ti
n ja, ati pe baba to foun lagbara toun n lo lo so pe ko seni to le ri oun mu,
lai mo pe omi si ma a pada wo igbin lenu.
Leyin naa ni Komisana olopaa pase pe kawon
olopaa SARS lo wa a wa, sugbon ti won loon a papa bora, ko too dip e asiri e tu
si won lowo pelu ore e kan ti won poruko e ni Quam Olubodun, omo ogun odun.
Nigba
to n ka boroboro, Spartacus so pe oun kii gbo ebe nigba toun ba ti n fa wahala,
toun yoo si rii pe oun gbemi lenu eeyan, ati pe oun ko le kawon eeyan toun ti
pa lekun.
Titi
di bi e ti n ka iroyin yi lo si fi wa logba SARS , to n gbategun, to si tun fawon
olopaa lowo lori bi won yoo se ri awon to ku e mu.
No comments:
Post a Comment