OMI TUNTUN TI RU LEGBE OSELU APC IPINLE OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 20, 2018

OMI TUNTUN TI RU LEGBE OSELU APC IPINLE OGUN

...Adebiyi di alaga tuntun, bee ni Fadairo di igbakeji e

Titi di bi e ti n ka iroyin lawon omo egbe oselu APC nipinle Ogun si fi n dupe lowo Gomina Ibikunle Amosun fun ti aseyori idibo ita-gbangba to waye lati fi yan awon oloye tuntun ti yoo tuko egbe naa fodun merin.

Idibo naa to waye ni gbagede asa ti Cultural Center to wa ni Kuto, Abeokuta lojo Abameta Satide to koja yi la gbo pe ko ni awuruju tabi oselu ninu pelu iranlowo Dokita Peter Obadan to je alaga eto idibo, iyen INEC fun ti idibo naa.

Gege b'AWIKONKO se gbo, awon omo egbe APC to fi die le ni egberun kan aabo (1,749) kaakiri ibile Ogun to wa jipinle naa la gbo pe won peregede lati dibo lojo naa fun ipo merindinlogbon (26) yo sofo, ti gbogbo won si dibo bo ti to ati bo ti ye lai ni konunkoho kankan ninu.

Leyin idibo naa ni Dokita Peter Obadan to je alaga eleto idibo naa kede sita pe oludamonran pataki fun Gomina lori oro oselu (Political Affairs), Oloye Samuel Aderionla Adeniyi lo jawe olubori gege bi alaga tuntun pelu ibo 1,712.

Obadan so pe yato si alaga tuntun naa, Alaaji Bashiru Fadairo naa wole gege bi igbakeji alaga egbe naa pelu ibo 1,709 nigba ti Onarebu Patrick Ogunde jawe olubori gege bi akowe egbe pelu ibo 1,710.

Bakan naa ni Onorebu Akeem Fagbemi di akowe; Onorebu Femi Ogunkoya di akowe owo; Onorebu Wole Elegbede to je akowe ipolongo; Ogbeni Folarin to je alabojuto omo egbe (welfare) atawon min in.

Saaju ninu oro e, Peter Obadan nigba to n soro gboriyin fun egbe oselu APC ipinle Ogun, paapaa Gomina Amosun fun ise takuntakun ti won n se lati je ki alaafia ati isokan joba ninu egbe naa.

O ni inu oun dun fun ipo toun ba egbe APC ipinle naa nitori pe ko ri be e lawon ipinle min in kaakiri orileede yi. Bee lo so pe ko si iye meji pe egbe APC nikan legbe to wa nipinle naa.

Nigba to n dupe lowo awon omo egbe naa, Oloye Samuel Aderinsola Adebiyi to je alaga tuntun naa so pe inu oun dun lori ona ti won fi gbe eto naa kale, ti ko ni awuyewuye ninu, tawon eeyan si le jeri sii pe oun loun wole.

O loun setan lati mu idagbasoke, ilosiwaju, isokan, ife ati alaafia ba egbe naa, toun yoo si tun tesiwaju nibi ti alaga ana ba a de. Bee lo fokan awon omo egbe bale pe egbe naa ni yoo jawe olubori lodun 2019.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun naa gboriyin fawon omo egbe, paapaa awon eleto idibo naa fun ise takuntakun ti won se lati rii pe eto idibo naa lo ni irowo-irose.

O gbawon omo egbe lamoran pe ki won rii daju pe won loo gba kaadi idibo alalope (PVC) won, ki won ba a le kopa nibi eto idibo odun 2019.

Lara awon to tun wa nibi eto naa ni Mustapha Gaidam (akowe); Ogbeni Ezekiel lati Taraba; Onorebu Dairo lati Kano; Umar Yahaya lati Kaduna; Dokita Keadese Adeola to se alaga eto idibo odun 2018; Alaaji T.T Ahmed to lewaju awon ajo INEC lati wo bi nnkan se n lo si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI