Ko seni to gbo bi gbajumo osere tiata ni, Ogbeni Kayode Odumosu
topo awon ololufe e mo si Pa Kasumu se n soro lai pe yi, nile to n gbe ni
Mowe-Ibafo, ipinle Ogun lose to koja yi, ti aanu ko nii se e, paapaa nigba to
tun so pe ko seni to ranti oun mo laarin awon ti won jo n sise tiata kaakiri
orileede Naijiria, paapaa loke-okun.
Pa Kasumu to lodun 1973 loun bere ise tiata nigba to n b’AWIKONKO
soro, to tun fe e le maa yo omi loju so pe oun si nilo iranlowo owo fun aisan
oju to n ba oun finra, bo tile je pe omo oun ko nife sii pe koun maa toro owo
lowo awon eeyan, sibe, ko si nnkan toun tun le se ju koun rawo ebe sawon omo
Naijiria lati ma je koun ku lasiko yi. E ka bi iforowero naa se lo.
AWIKONKO: Oruko yin lekunrere ati
bi e se bere ise tiata?
PA KASUMU: Oruko mi ni Olukayode Olugbenga
Odumosu. O ti le logota odun ti won ti bi mi. omo bibi ipinle Ogun ni mi. Baba
mi wa lati ilu Odogbolu nigba ti Mama mi je omo Egba niluu Abeokuta. Mo saba
maa n pe ara mi Ijegba (Ijebu-Egba). Odun 1973 ni mo bere ise tiata ni kikun.
Nigba yen, mo je okan lara awon osise ileese awako kan niluu Eko. Iporin ni mo
n gbe. Nigba ti n ba n bo lati ibise, mo maa n ri awon eeyan ti won n se ere
ori itage.
Mo so si okan mi pe oye ki emi naa le darapo mo won, ki n si se
daadaa pelu ise yen. Mo loo ba adari egbe yen lati so erongba mi, lesekese lo
gba mi. Bi mo se fi ise ti mo n se sile niyen ti mo si bere pelu won. Nigba ti
mo bere, o dun mo mi gan an, mi o ri gege bi nnkan babara tabi nnkan to le. Mo
nilo owo nigba yen, eyi lo je ki n fi ise ti mo n se tele sile, ki e si maa wo
o, nigba yen, owo gidi wa ninu ise tiata nigba yen.
AWIKONKO: Nje ise tiata ti e ko
ipa to joju nigbesi aye yin, ati pe inu egbe osere wo leyin wa?
PA KASUMU: Beeni, ise tiata se pupo ninu
igbesi aye mi gan an. O je ki oju mi la sawon nnkan to sokunkun, o tun je ki n
gbon ju bi mo se lero lo. E je ki n jewo fun un yin, mo ko eko pupo lara awon
ta a jo n sise tiata. Igbe aye won yato si ara won, bee naa ni ihuwasi won ko
jo ara won rara. Mo ti bawon se egbe ANTP. Mi o lero pe egbe naa si tun wa mo.
Egbere osere TAMPAN ni mo tun n gbo bayii, awon osere Yoruba nikan lo si wa
fun.
Okunrin kan ti won n pe ni Afolabi lo ko mi nise tiata. Oun lo ni Simbad Concert. Olorun Egbon lo ko
Afolabi nise. Mo kopa ninu orisirisi ere ori itage ati sinima repete bii
Wole-Wole, Arufin, Iyawo Orun. Iyawo Orun yi gan an lo gbe mi si aye, oun lo je
ki n di ilumon on ka. Nigba ti won maa se fiimu yen, won n wa enikan ti won le
lo lati ko ipa kan, mo ni lati fi ara mi sile pe mo le se e, won si yan mi. Mo
se daadaa, inu oga mi si dun debi pe, o patewo fun mi, o tun bo mi lowo. Nnkan
iyi gidi ni nigba yen.
AWIKONKO: Ki lo fa aisokan ati
eleyemeya laarin awon osere tiata lorileede Naijiria?
PA KASUMU: Awon osere tiata soro lati ko
won papo jo soju kan naa. Boya le mo pe latigba ti mo ti wa nibi (Mowe) yi
latari aisan ti mo ni, ko si eyikeyi ninu awon osere tiata to ti yoju si mi
lati wa se abewo si mi. Ko da nigba ti mo si wa niluu Abeokuta, mi o ri
enikeni, bo tile je pe pupo ninu won lo n gbe Abeokuta. Aisokan to wa laarin
won lo da eyi sile. O see se ko je pe ilara lo fa oro aisokan yi, Olorun nikan
lo ye. E wo Olumide Bakare. E wo opolopo ojo to lo ni osibitu ko to o ku, mi o
lero wi pe a ri enikan ninu awon onise tiata to lo o yoju sii. Bo tile je pe asiko
yen gan an ni aisan ara mi le gidi, sibe mo si tun n gbiyanju lati rii pe a n
soro latigbadegba daadaa.
Oro ti Pasito Ajidara naa je nnkan to ba mi ninu je d’okan, to si
dun mi wonu egungun gidi. To ba je pe se la wa papo, o see se ko je pe nnkan to
dojuko le ma pada seku pa a. E wo emi naa bayii, awon elegbe mi ti pa mi ti, o
je nnkan to buru jai, sugbon mo dupe pea won ebi mi ko pa mi ti. Mi o le gbagbe
awon to ti ku bii Olumide Bakare ati Pasito Ajidara.
AWIKONKO: Ki ni pataki aisan to n
se yin?
PA KASUMU: Aisan to n se mi nii se pelu oju
mi, mi o riran daadaa bii ti tele mo. Nnkan maa n di pupo loju mi ni. Bi e se
duro ti e n ba mi soro yi, se lo dabii pee yin meji le duro niwaju mi. Mo fe e
dupe lowo omo mi. o duro ti mi pelu orisirisi adojuko ati ipenija, to n mu mi
lo lati-ibikan si ibomin in. mo ti lo s’ibi kan ti won ti n se oju n’Ikoyi. Mo
ti lo si India fun itoju. Odun mesan seyin ni wahala yi bere, iyen lojo kesan
an osu kejila odun 2009.
Nigba to bere, omo mi nikan lo duro ti mi, o je omo to ni irele.
Mo n san egberun merinlelogbon (34,000) naira si egberun merindinlogoji
(36,000) naira lose-ose fun itoju. Nigba yen, mo si ni awon owo kan ninu apo
ile ifowopamo (Bank Account) mi, mo ri awon owo yen pelu bi
mo se gba’le-gba’ta. O ye ki n na owo yen, sugbon mo fe e fi owo naa kan paanu
ile mi ti mo n ko si agbegbe Ogijo ni, owo naa to milionu merin (#4) naira.
Sugbon nigba ti aisan yi de, gbogbo owo yen lo lo si patapata.
AWIKONKO: Se ka so pe ajalu to wonu egbe
osere lowo aye ninu ni, nitori pe a gbo ti Moji Olaiya, Olumide Bakare, Pasito
Ajidara atawon min in bee na?
PA KASUMU: Kii se awa osere nikan. Gbogbo
eeyan kaakiri-kaakiri ni. Mi o ri gege bi ise aye, nitori pea won osere kan naa
si wa, ti won ko gbajumo, tawon naa ti ku latari aisan to kolu won. Ni temi, mo
si n dupe lowo Olorun nitori pe lati bii odun mesan an seyin, bi Olorun ko ba
si ni emi mii lo, ko nii da mi si titi dasiko yi.
AWIKONKO: Ni bayii, e o se sise tiata mo.
Nje a le ri eeyan ti yoo tun maa ko awon ipa ti e ko tele, abi majiiki kan wa
ninu aseyori yin?
PA KASUMU: Ni temi o, Olorun ni. Bi a ba n
so nipa boya a tun le ri eni ti yoo sebi temi nidi ise tiata. O le gba opolopo
asiko, sugbon sibe, enikan, nibikan si maa gba ipo yen, teni naa si maa se e
daadaa. E gbo o, mi o tii ku bayii. Mo si ni afojusun. Mo si ni ireti pe mo si
maa fi ese mi mejeeji rin. Mo si maa pada sidi ise tiata bi ara mi ba ti ya.
Ko si nnkan to se ese mi, bo tile je pe mi o le rin daadaa,
die-die ni mo n rin, sugbon, sugbon mo nigbagbo pe Olorun oluwosan yoo gbakoso.
Bi e ba n wa eni ti yoo wo bata ti mo ba bo sile nidi ise tiata, o le gba
asiko. Mi o mo. Sugbon ti e ba n so pe ko seni to tun le wo bata yen, e je ki n
so fun un yin pe a ni awon osere ti won le se e. Bi ile aye se wa niyen. Ko si
nnkan to je babara ninu ipa ti mo n ko.
AWIKONKO: Bi eelo le nilo bayii lati toju
ara yin ati pe awon wo lo ti ran yin lowo tele?
PA KASUMU: Mo so fun un yin tele pe mo ti
lo si India. Won gbiyanju agbara won. To ba je pe mo ri anfaani lati tun pada
lo leekeji to ye ki n pada lo ni, o see se ki nnkan ti yi pada si daadaa. Mi o
le pada lo nigba yen nitori pe mi o ri owo lati lo. Milionu meji ataabo (#2.5)
naira ni owo ti mo koko fi lo, sugbon eleekeji to ye ki n pada lo, milionu meji
din legberun lona igba (#1.8) naira ni mo nilo, sugbon ti mi o pada ri ko jo.
Owo yen le ti tun han si pelu eto oro aje wa. Inu mi i ba dun ti n ba tun ri
anfaani lati pada lo. Sugbon nnkan to n kan mi lominu ni pe se ni won tun sese
maa bere itoju mi lat’ibere.
Owo ti mo maa nilo bayii ko le ju milionu meji (#2) naira lo, lati
ra oogun. Awon oogun ti mo n lo hang an, owo won ti han ju. Egberun mejila
(#12,000) naira ni eyokan ninu won. Bo tile je pe omo mi ko feran ki n maa toro
owo sugbon ko si nnkan ti mo fe e se mo bayii ju ki n soro sita lo, nitori pe
mi o le da se. Mo ti loo ba enikan lagbegbe Meiran nipinle Eko, ti eni naa so
pe oun yoo gba idaji milionu (#500,000) naira lowo mi. se eyin naa ri ara nnkan
ti mo n la koja bayii.
Nipa awon to ti ran mi lowo, Gomina Ibikunle AMosun tipinle Ogun
ti se bebe fun mi ri, o ti fun mi lowo nigba kan ri, bee lo tun selerin fun mi
pe oun yoo sabewo si mi, to si mu ileri e se. Yato si Amosun, Gomina tele ri
nipinle Eko, Babatunde Fashola naa ti se daadaa si mi. Ilu Meka lo wa, to ti
gbo iroyin aisan mi, to si ran awon eeyan pe ki won wa a wo mi, awon to ran wa
lo mu mi lo si First Cardiology to wa ni Ikoyi, bee lo tun fun mi lowo. Bee ni
Gomina ipinle Oyo tele, Oloye Alao Akala leni to koko fun mi lowo. Mo dupe lowo
gbogbo won, sibe-sibe, mo si n nilo iranlowo yin.
No comments:
Post a Comment