Bo tile je pe kii se oro owo ni iyaale ile kan,
Arabinrin Asimiu Labake gbe lo sile ejo koko-koko to wa ni Ake wi pe ki won tu
igbeyawo to wa laarin oun ati oko oun, sugbon nigba to n ro ejo e ni asiri oro
naa je jade sita, to si se awon ero iworan ni kayeefi.
Ojo Tusde ose ta a lo tan yi ni Labake soro niwaju
awon adajo kootu pe odun 2014 loun ti ko eru jade kuro nile oko oun, nitori pe
se lo fe e pa oun patapata, ko si maa baa won obinrin min in jaye kaakiri, eyi
to mu ko maa ba oun fa wahala lojoojumo.
Labake so pe oun ko tete mo pe oko oun ba omo baba
onile awon sun, to tun n ko ibasun fun okan lara awon omo Imaamu Asalatu won
karakara, sugbon nigba ti wahala nla kan sele laarin won lasiri oro naa tu jade
sita, tawon araadugbo si wa a jeri tako oko oun pe agbere e ti po ju ladugbo,
ti ko si seni ti ko le denu ife ko.
O ni nigba tawon pari ija naa loun pe oko oun,
Tajudeen Sanusi pe ko je kawon loo gba ile sadugbo min in, tawon si jo panupo
gba owo LAPO ti won n ya awon eeyan ladugbo. O ku ola ki won gba owo naa lo so
pe egbon oko oun tomo e fe e seyawo pe oun pe oun gbo pea won fe e ya owo,
nitori naa tawon ba ti gba owo naa, koun ya won lati lo fi mu aso pati, leyin
pati loun yoo si da owo naa pada.
Labake so pe lojo toun gba owo naa, se lawon
adigunjale gba owo naa lowo oun, ti oko oun ko si da oro owo naa so, titi toun
fi san owo naa ku egberun mewaa naira, ati pe nitori koun ba a le ri owo san
loun se kuro nile lati loo wa ise min in se.
O nigba toun maa pada de loun rii pe oko oun ti ta
soobu oun, iyen kontena toun n lo, ti ko si ko owo naa kale, sugbon to loo san
egberun mewa naira gbese to ku, ti ko si ko owo naa foun, o nironu owo naa lo
moun daku tawon araadugbo sis are gbe oun lo si osibitu, sibe oko oun ko yoju
lati wa a wo oun. O ni ojo keta toun pada dele loun ko eru kuro nile, toun si
wo o pe bi awon ko ba yanju oro naa laarin odun merin, oun yoo jawe fun un.
Baale ile naa, Sanusi so pe oro asodun niyawo oun so
nitori pe lojo to maa ko eru e jade kuro nile, alejo kan loun sin jade lo,
nigba toun maa pada dele, loun rii pe ile ti mo, awon araale lo so pe iyawo oun
ti keru jade. O ni lojo yen, aburo iyawo oun lo wa ki awon nile, asiko naa
kisiini loun wa toun n dana lowo.
Awon ta a jo n gbe so pe ki lo de toun ko le beere
nnkan ti aburo iyawo oun maa je, toun si dawon loun pe ki lo de ti aburo naa ko
le wa a ba oun nibi toun ti n dana, aburo naa lo so pe o bere sii pa asamo
moun, to si fibinu soro sii, leyin naa lo so pe oun jade, nigba toun si maa
pada dele loun ko baa won mejeeji.
Oloye Akande O. O. nigba ti won soro so pe bo tile je
pea won ko le da ejo lojo kan soso, sibe kawon mejeeji loo tun ero won pa
daadaa boy a atunse si le wa ko to o di ojo kejidinlogun osu karun un (May 18)
ti igbejo min in yoo fi waye.
No comments:
Post a Comment