Kani okunrin olokada kan ta a ko tii
mo oruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan mo pe ise pajawiri ti won pe e si
maa pada sakoba fun un lojo naa, boya ko ba ma ti se e, tabi ko ma dahun nigba
ti won pe e.
Beeyan ba je ori ahun, to ba de
agbegbe iyana Amolaso nitosi Kuto lojo Monde ose to koja lo lohun nibi ti tirela ti
te olokada naa, ti ese e si kan lesekese, eni naa yoo ba a kaanu.
Ni nnkan bi aago mewaa aabo aaro la
gbo pe olokada ta a ko tii mo oruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan n fi
okada sise oojo e gba agbegbe Kuto koja lo, sa dede ni won so pe okunrin kan da
a duro nitosi Cultural Centre pe ko gbe oun.
Bo se gbe e ni won so pe okunrin naa
so fun olokada yi pe ko ba oun le tirela to ko lu moto oun, to si ti ba a je
koja siso, toun naa ko si ro o leemeji, to gba to tirela naa leyin.
A gbo pe bi won se de iyana Amolaso
ladojuko ile epo kan ta a foruko bo lasiri ni won so pe olokada naa fe e gba
egbe e, ko si le bo siwaju e, sugbon to je pe abe taya e lo ko si.
Bo se ku die ki olokada naa ko sabe
taya tirela naa ni won so pe okunrin to wa leyin e ti fo danu, to si f'apa bo,
ti olokada ni tie ko save tirela, tiyen si te ese e kan sile.
Lesekese la gbo pe ati okunrin to
ran olokada nise de torutoru, ati okunrin to wa tirela naa ti na papa bora, ti
ko seni to mo bi won se rin in lakoko tisele maa sele.
Nibe lawon toro naa soju won ti
ranse sawon olopaa atawon TRACE lati wa a gbe olokada naa, sugbon nnkan to je
iyalenu ni pe fun bi wakati kan aabo la gbo pe awon olopaa atawon TRACE naa ko
ri nnkan se sii, ko too di pe awon tisele naa soju won fi agidi da moto taisi
kan duro lati bawon gbe e lo si jenera osibitu Ijaye fun itoju.
Awon kan to n fehonu won han lori
iwa ti eni to wa tirela naa hu fe e dana sun tirela yi, sugbon awon olopaa
atawon TRACE ni won ko gba fun won, ti won ni awon yoo sewadi.
AWIKONKO pada gbo pe awon osise
osibitu jenera so pe awon ko le gba a, eyi lo muu ki won gbe e lo si FMC to.wa
ni Idi-Aba, nibe lo dake ki won to o gbe wonu woodu.
Ojo keji la gbo pe won sin in nilana
musulumi ladugbo Amolaso. A tun gno pe iyawo meji pelu omo meji lo ni, yi okan
ninu awon iyawo naa n gbe ladugbo Ake, sugbon ta a ko tii mo oruko e dasiko ta
a sakojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment