Egbe awon to n
ta oogun oyiin oyinbo lorileede Naijiria, Nigerian Association of Patent and Proprietary Medicine
Dealers (NAPPMED), eka tipinle Ogun ti bere eto ipade olodoodun won, eyi ti won
n lo lati fi dawon eeyan lekoo lorisirisi, paapaa nipa lilo oogun oyinbo lona
to to ati eyi to ye.
Eto olojo meta naa to
bere lonii ojo Tusde la gbo pe won fi n gbalejo Aare egbe won, Omoba Joel Odoh
ati akowe egbe naa, Onarebu Tunde Oke atawon omo oloye egbe naa kaakiri
orileede yii.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo, won ni iwode ita gbangba ni
won fi side eto naa ti won pe akori e ni Challenge of “Health for All”
in Nigeria, eyi ti won se ni agbegbe Party Park Arena ninu ogba papa isere
ti MKO to wa ni Kuto, Abeokuta.
Yato si awon omo egbe naa to n bo kaakiri orileede Naijiria, awon
bii Minisita for ilera lorileede yii, Ojogbon Isaac Folorunso; Komisana feto
ilera nipinle Ogun, Ogbeni Babatunde Ipaye; awon osise ajo NDLEA ati NAFDAC
atawon min in ti ise won nii se pelu oogun oyinbo la gbo pe won maa dawon eeyan
lekoo lakoko tie to naa ba n lo lowo.
A gbo pe ojo Wesde ogbon ojo ati ojo Tosde ojo kokanlelogbon
ni won yoo tun tesiwaju ninu eto naa ni gbongan ayeye Providence to wa lagbegbe
Leme niluu Abeokuta laago mejo aaro.
No comments:
Post a Comment