Morufu fe e ko iyawo e sile nitori agbere - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 8, 2018

Morufu fe e ko iyawo e sile nitori agbere

Ko seni to le ba baale ile kan, Ogbeni Morufu Omidiji soro mo pe ko gba iyawo e to bimo meji fun un pada sile pelu bo se n soro nile ejo koko-koko to wa ni Ake niluu Abeokuta laaro ojo Tusde ose to koja yi, to si n be awon adajo pe ki won tu igbeyawo to wa laarin oun atiyawo oun ka.

Ko si nnkan meji to je ki baale ile naa so pe oun fe e ko iya awon omo oun sile bi ko se ti iwa agbere to fi kan an wi pe boun ko ba tete ko o sile, o see se ko ran oun lo sorun apapandodo losan gangan, toun ko tii jaye ori oun daadaa boun se fe e.

Morufu tojo ori e ko tii ju odun metadinlogoji lo nigba to n soro so pe bo tile je pe awon ko segbeyawo kawon to o gbe ara won sile, sugbon ko seni ti Iyabo Mimiola Omidiji ko le gba fun bi won ba denu ife ko o, ti won yoo si ba a sun karakara.

O ni oyun akoko to maa koko ni, okunrin kan lo nii fun, bo tile je pe omo naa pada ku lojo to bii pelu ise abe, sibe awon ebi e atawon ore oun lo so pe won ba a bebe pe koun gba a pada sile, ko pe sigba naa lo loyun foun tawon si n gbe igbe aye alaafia.

Baale ile na so pe nnkan to tun dun oun ju ni biyawo oun tun se loo loyun fun ore oun timo-timo, sibe opolopo osu loun fi le e jade kuro nile, toun ko si mo bo se se oyun naa, ko to o di pe won tun be oun lati gba a pada.

Eyi to niyawo oun se gbeyin to mu koun le e danu, toun si fi fe e ko sile nib o tun se lo n sun lodo okunrin kan to je aburo egbon oun lasiko odun to koja, iyen osu kinni in odun yi, nigba to lo o ba mama oun sodun nile won.

Awon araadugbo lo so pe won ta egboun naa lolobo, ko da a, to ni iyawo eni to n ko ibasun fun iyawo oun tun wa a fejo sun, eyi to mu ki won pariwo le e lori ladugbo ko tete gbe eru e kuro, ko gba ibi to ti wa lo.

Nigba toun naa n soro, iyaale ile naa, Arabinrin Iyabo Mimiola to so pe ise ogun (Chemist) loun n se so pe iro ni oko oun n pa, ati pe oun ko ri idi kan ni pato to fi fe e ko oun sile, nitori pe kii toju oun atawon omo. O ni latigba to ti le oun jade, inu soobu loun n sun pelu awon omo naa, igba to mu iwe kootu wa foun losu to koja loun ko ti gba ko foju kana won omo naa mo, nitori won maa n lo sodo e lojoojumo tele.

Awon adajo ile ejo naa, Oloye Akande O. O. ati Onarebu Arabinrin Majekodunmi H. I. ninu oro won ni won ti gba iyaale ile naa lamoran pe ko loo jawo ninu iwa palapala nitori pe gbogbo nnkan ni oko e fi te e lorun, ati pe ki lo n wa lara okunrin min in ti ko si lara oko e.

Fun idi eyi, won ti sun ojo igbejo min in si ojo kejilelogun osu karun (May 22), bee ni won so pe ki Morufu lo o toju awon omo naa, ki Iyabo si je ki baba awon omo maa ri awon omo e lasiko to ba wuu ko to o di ojo idajo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI