Adije sipo gomina ipinle Osun lodun 2018 ta a wa yi, Seneto Iyiola Omisore to tun ti figba kan ri je igbakeji gomina ipinle naa ti kede sita pe oun ko le tesiwaju lati maa segbe oselu PDP, nitori naa, egbe oselu Social Democratic, iyen SDP loun fe e ba lo.
Aaro oni, Sande ni Omisore gbe atejade naa sita fawon oniroyin niluu Osogbo pe lati le je ki ipinu oun lati gba ijoba kuro lowo oselu APC, koun si di gomina wa si imuse, ko si nnkan meji toun tun le se ju koun fegbe naa sile lo.
O loun se tan lati fa ipinle Osun yo kuro ninu koto iparun tijoba to wa nibe bayii n tii si, kawon araalu si le je mudun-mudun eto oselu ijoba awaarawa.
Ko si nnkan meji to n ya opo awon eeyan lenu, bi ko se awon ipa ti won ni Omisore ko ninu egbe naa, to si je pe asiko to ye ko maa je awon eere ise owo e lo wa deede pinu lati fi egbe naa sile.
Ohun tawon eeyan n so ni pe wahala to n sele ati bi enu awon omo egbe naa ko se ko lo mu ki agba oloselu naa fegbe sile, ki won ma ba a koba ipinu e lati di gomina.
No comments:
Post a Comment