ILE EJO TU IGBEYAWO OSU MESAN KA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 8, 2018

ILE EJO TU IGBEYAWO OSU MESAN KA

Opo awon ti wa ni kootu koko-koko to wa ni Ake lo min ori won nitori to se won ni kayeefi repete pelu bi awon adajo meji ileejo naa se tu igbeyawo osu mokanla to wa laarin Baale ile kan, Yusuf Lawal ati iyawo e, Isiwatu Lawal ka pe konikaluku won maa lo lotooto pelu alaafia.

Lawal, eni odun marundinlogbon (25), to ni ojule ketalelogoji, adugbo Sapon loun n gbe lo mu ejo lo si kootu pe iwa iyawo oun, Isiwatu ko te oun lorun mo, ko si kii gboro soun lenu mo ninu ile, toun ko si le gba a mora mo.

Baale ile naa to so pe ise kafinta loun n se nigba to n fi Kuraani (Quran) bura niwaju ileejo so pe Isiwatu ko nitelorun to kere ju, boun ba si soro, se lo maa dide gba oun leti, to tun maa fa aso ya moun lorun, to je oro awon ti su awon araale to maa n ba won da si.

O lawon ti welfare ti won si so pe koun maa san egberun marun naira nitori omo kan soso, Lawal Amudala, omo osu mejo to si n mu oyan lowo to n to lowo, toun ko si le salai ma san an, nitori pe kii se pe nitori pe oun ko fe e gba omo lowo e loun se fe e ko sile.

Bee lo so pe gbogbo igba loun maa n pe e bo tile je pe oun ko foju kan an lati bii osu meji seyin, to si maa n so pe alaafia ni omo naa wa foun. O je ko di mi mo pe latigba tawon ti kuro ni kootu lojo tawon wa gbeyin ni ko ti wa a fa wahala mo nibi toun n gbe

Bo tile je pe Iyaale ile naa ko yoju, sugbon ti won jo wa si kootu leemeji otooto ti won bere ejo naa, tawon mejeeji si gba lati ko ara won sile, sibe awon adajo naa so pe ko si nnkan tawon fe e se ju ki onikaluku won maa lo lotooto lo pelu ayo ati alaafia.

Bee ni won pa a lase pe ojo kojo ti Isiwatu ba ti loo fa wahala lodo oko to ko sile, ki won loo fi olopaa gbe e, nitori pe ileejo tit u won, bee ni won so pe baale ile naa ko gbodo salai ma san owo ti won ni ko maa san, o si lase lati beere omo e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI