Lojo Tusde ose to koja yi ni ile ejo koko-koko to
fikale si adugbo Ake niluu Abeokuta tu igbeyawo odun mejidinlogun (18) to wa
laarin iranse Olorun kan, Ogbeni Moses Oseyemi atiyawo e Arabinrin Temitopo
Oseyemi ka, ti won si tun pase pe ki okunrin naa ko awon omo e mefeefa sodo
lati maa toju won.
Kii se pe ile ejo naa deede wo sunsun lati tu igbeyawo
naa ka, sugbon aiyoju iyaale ile naa leemeeta otooto ti won fiwe pe e wa si
kootu lo mu kawon adajo naa, Oloye Akande O. O ati Onarebu Arabinrin
Majekodunmi H. I fagile igbeyawo na pe ki onikaluku won maa lo lai si wahala.
Nigba to n bura niwaju ile ejo pelu bibeli, Moses so
pe “Adugbo Sabo niluu Abeokuta ni mo n gbe pelu awon omo mefa, ise Pasito ni mo
n se, mo si tun n sise owo pelu e. Mo fe ki ile ejo tu wa ka, ki won si ko awon
omo mi fun mi lati maa toju won, bo tile je pe akata mi ni won wa. Orisirisi
iwa adojutini niyawo mi n hu, to si maa n ba mi fa wahala to po. Lojo to maa ko
eru e jade lodun 2016, se lo loo gbe omo wa abigbeyin toun ti pe odun meji aabo
bayii sile fun araadugbo pe oun n bo, latigba naa ni ko ti yoju, to je pe okan
lara awon omo ijo mi lo n ba mi toju omo naa.”
O ni ko to o di pe oun wa si kootu loun ti loo fejo e
sun awon ebi, nitori pe awon loun maa n pe nigba tawon ba ti ni ija, sugbon
nitori ko si ayipada lo mu koun pinu lati ko o sile labe ofin. Bee lo so pe o
see se ko ti fe okunrin min in nitori pe latigba to ti ko omo sile foun ni ko
ti yoju lati wo alaafia awon omo e.
Nigba to n gbe idajo kale, Oloye Akande O. O ati
igbakeji e, Onarebu Majekodunmi H. I. je ko di mi mo pe bawon ko ba ti ri eni
ti won fesun kan leemeeta otooto tawon ba ti fiwe pe, a je pe eni naa ti gba
kamu pe kile ejo se nnkan to ba ye.
Oloye Akande so pe ojo kejilelogun osu keta ati ojo
kokandinlogun osu kerin lawon fiwe pe e, tawon si tun reti e lati wa a so tenu
e lojo Tusde naa, sugbon ti ko yoju, o ni ko si nnkan tawon yoo se ju kawon tu
won ka gege bi oko se n fe lo.
No comments:
Post a Comment