Ile ejo tu igbeyawo odun marunlelogoji ka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 14, 2018

Ile ejo tu igbeyawo odun marunlelogoji ka

 ...Mi o le fi oko mi sile lailai – Iyaale ile

Ko seni to wa nile ejo koko-koko to fikale si agbegbe Ake niluu Abeokuta lojo Tosde ose to koja yi, iye ojo kewaa osu yii to gbo bi iyaale ile kan tojo ori e ti le logota odun, Oloye Arabinrin Janet Alawode se n fomije soro niwaju ile ejo pe oun ko le gba ki oko oun foun sile nirole ojo aye oun nitori pe odun marundinlaadota (45) gbako loun fi sin oko oun ti omije ko nii jabo loju oun naa.

Oko Janet, Oloye Matthew Alani Alawode, eni odun mokandinlaadorin (69) lo sare lo sile ejo pe ife to wa laarin oun atiyawo oun ti ku, nitori naa loun ko se le ba a gbe mo, ko si yo oruko e kuro ninu oruko oun.

Ko si nnkan meji taa gbo pe o fa a ti baba agbalagba naa se pinup e kiyawo oun maa lo, bi ko se bo se so pe obinrin ti ko ba ti le ba oun bo orisa toun n bo, ko le ba oun gbe inu ile tabi ko si tun maa je oruko oun.

Nigba to n soro, Oloye Matthew Alani Alawode so pe “Gege bi oruko mi, Alawode, ifa ni a n se nile wa. ati Kirisiteeni, ati Musulumi, gbogbo won ni won ni orisa ti won n bo nidile ti won. Mi o ni ejo pupo lati ro niwaju ile ejo, nitori pe ko si nnkan to le yi ipinu mi pada si bi mo se fe e se nnkan mi. Mo n lo soosi, iyen ko so pe ki n ma bo orisa, tiyawo mi naa si gbodo se e, bi ko ba le se e, ko si nnkan to tun n duro se nile mi. Mo fun ni anfaani pe ko maa gbe fulaati oniyara meta to n gbe nile ti mo ko s’Ekoo, sugbon ko gbodo de awon fulaati to ku lati gba owo lowo awon ayalegbe to wa nibe nitori pee mi ni mo nii.”

Iyaale ile naa, Oloye Janet Alawode to so pe omo bibi ipinle Delta loun so pe oun ko setan lati fi oko oun sile nitori pe awon kii loko meji nibi toun ti wa, ati pe nibo loun fe e gba leyin toun ti jise jiya bi omo mejo foko oun, to ti lo gbopgbo adun aye oun tan, to wa fe e ja oun ju sile nirole ojo.

Janet tesiwaju pe Kirisiteeni loun, latigba toun ti fer oko oun loun ti n ba a se orisa to n se, sugbon nigba to ya, ti ara oun ko gba bi won se n se orisa naa mo, loun pinu pe  oun sin orisa kankan mo, iyen lodun merin seyin.

O ni Matthew lo gba ibale oun, toun si fi gbogbo aye oun sin in, tawon si jo ni dukia repete kaakiri ilu Eko, Abeokuta atawon ilu min in tawon ni dukia si, to tu8n je pe gbogbo omo tawon bi ni won ti wa laaye ara won, ti dokita, enijina, agbejoro si wa ninu won.

O tesiwaju pe leyin igba toun pinu lati ma se orisa naa mo loko oun ti ya yara foun, ti ko jeun nile mo, ti ko si tun ba oun lasepo mo, toun si fara mo be wipe nnkan si ma yipada to ba ya, sugbon iyalenu ati ipaya lo je foun nigba toun ri leta ikosile lati odo oko oun.

Janet tun so pe yato si pe oko oun fe e ko oun sile, o tun fe e gba gbogbo dukia tawon joo jise jiya fun, peluu ile kan toun ra siluu Abeokuta, leyi to so pe ko boju mu, toun ko si nii gba. Bee lo so pe nibi toun nife oko oun de, ko si eyikeyi ninu awon omo won to mo nnkan to n sele laarin won.

Meji ninu awon omo won, Arabinrin Olubukola Anike Ogunkoya, eni odun mejidinlogoji ati Dokita Adesola Alawode to wa nile ejo lojo naa so pe looto ni ede aiyede wa laarin awon mejeeji lodun merin seyin, tawon si ba won yanju e, lai mo pe nnkan min in si n lo laarin won labele.

Won niyalenu lo je nigba ti iya awon pe awon lori aago lose meji seyin pe awon wa ni kootu lojo ketalelogun osu to koja pe baba awon fe e ko won, tawon si n sunkun nibi tawon wa.

Won je ko ye ile ejo pe bo tile je pe awon ko si nibe nigba tawon mejeeji bere ife won, sube awon ko le so pe kawon mejeeji ma se nnkan to maa te won lorun, ki alaafia le joba.

Ju gbogbo e lo, Aare ile ejo naa, Oloye Akande O.O ati igbakeji, Onarebu Arabinrin Majekodunmi H.I so pe bo tile je pe awon gbiyanju lati ba Oloye Matthew soro pelu bo tun se je okan lara awon Oloye to gbajumo daadaa niluu Abeokuta, sibe ofin ko faaye gba awon pe kawon ma se nnkan to maa mu alaafia ba ilu.

Won pase pe ki toko tiyawo naa bura, tawon mejeeji si bura peluu Bibeli. Bee ni won tu won ka pe onikaluku won lo letoo lati loo fe elomin in ti ko si gbodo si ija tabi aawo laarin won mo.

Nigba ti won n gba Iyaale ile naa lamoran, won ni idajo naa kii se opin nitori pe ise tijoba gbe le won lowo niyen, o ni aaye ati anfaani si sile fun Janet lati pe ejo kotemilorun laarin ogbon ojo (30days) to ba fe e gba oogun pelu bo se je pe oruko e lo wa ninu awon iwe ile ati dukia won.

Won nile ejo giga lo lase lati tesiwaju ninu iru ejo bee, tiwon ni ki won tu won ka, tawon ko lase lati bawon soro dukia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI