Bo tile je pe baale ile tojo ori e o tii ju odun
mokanlelogbon (31), Mutairu Afeez ko fara mo bi iyawo e ti won ti n ba ara won
bo lati odun marun seyin, Kuburat Ishola Afeez se so pe ki ile ejo tu won ka,
sibe ko si nnkan tile ejo le se lati tun je kife joba laarin won pada bii ti
tele, ti won si fi ida ofin ile ejo tu won ka lojo Tosde ose to koja yi.
Iyaale ile naa, Kuburat, to ni odun mejidinlogbon (28) ni ojo
ori oun lo mu ejo lo sile ejo koko-koko to wa ni Ake niluu Abeokuta pe ki won
ba oun tu igbeyawo odun marun to ti wa laarin oun ati oko oun, nitori pe ara
oun ko gba iya ajekudorogbo mo.
Kuburat so pe leyin toun gbe oko oun wa sile ejo, ti awon
adajo ni kawon pada lo sile boya oro naa le yanju, toun si ro gbogbo iwa buruku
owo oko oun yoo pada ro lara e, sibe bawon tun se kuro ni kootu lojo
kejidinlogun osu to koja, se ni oko oun tun bere sii lu oun, de bi pe se lo ja
oun sihoho omoluabi, tawon eeyan si n foun se yeye ladugbo.
Obinrin naa to je ko di mimo pe adugbo Soyoye loun n gbe
niluu Abeokuta, toun si n ta oogun (Pharmacy) ni ko si nnkan toun se niwaju oko
oun, to te e lorun ri, ti oun ko si le gba a mora mo, nitori naa ki onikaluku
maa lo nilo o layo ati alaafia, ati pe oju orun to eye fo lai fi apa kan ara
won.
Nigba to n soro, Baale ile naa Mutairu so pe iro nla ni
Kuburat pa mo oun nitori pe oun kii fiya Kankan je, ati pe iya e ni ko fe e je
ko ridi jokoo nile oko, nitori pe iwa toun ati iya e n hu ko te baba won, iye
Baba Kubura lohun, ti ko si fowo sii pe kawon tuka.
O ni oun ko lu iyawo oun lojo yen, nnkan to loo sele ni pe,
oloselu kan toun n ba sise lo ranse pe oun lori foonu pe kawon pade nikorita
kan, ibe loun wa ti omo to wa laarin won, Aishat to je omodun meta ti sare wa
ba oun, toun si n ba omo naa sere, gbara to so pe Kubura ri oun lo sare wa, to
si n pariwo mo oun pe se loun fe e ji omo gbe.
O lariwo naa po debi tawon araadugbo gan an wo o pe ki lo n
sele nitori pe se lo tun ranse pe iya e, ti won si wa n sepe foun, ti won tun n
lu oun. sibe o loun ko setan lati ko Kubura gege bi iyawo nitori pe oun si nife
e, sugbon toun faramo nnkan to n fe. Leyin o reyin lawon took-tiyawo naa fi
Kurani (Quran) bura niwaju ile ejo pe ko si iro ninu oro tawon so
Awon adajo ile ejo naa, Oloye Akande O.O ati Onarebu
Arabinrin Majekodunmi H.I nigba ti won n soro ti won bu enu ate lu iwa ti Mufutau n hu si iyawo
to bimo kan soso fun, bee ni won gba a nimoran pe ko loo jawo.
NIgba tawon mejeeji bura tan ni Oloye Akande O.O to je aare
ile ejo naa pase pe ile ejo tu igbeyawo won ka labe ofin, ti won si gbodo gba
alaafia laaye laarin ilu. O ni ki Mufutau wa maa san egberun merin (4000) naira
sile ejo naa losoosu fun itoju omo won, ati pe yato si eyi, awon mejeeji lo
leto lati gbo bukata omo naa yala lori owo ileewe, oro ilera e, atawon nnkan
min in tomo naa ba nilo.
Bakan naa lo tun pase pe igbakugba ti Mufutau ba fe e foju
kan omo e lo le ri.
No comments:
Post a Comment