Lojo Tusde to koja yi
nile ejo Majisireeti to fikale si agbegbe Ogba nipinle Eko pase pe ki pasito
ijo Irapada, iyen The Redeemed Christian Church of God, Paisto Jamiu Ishola Kolawole
loo gbategun osu mejidinlogun (18months) logba ewon lai faaye sile lati gba
beeli e.
Gege bi iroyin to te
AWIKO|NKO lowo se so, esun owo ti ko din ni milionu mesan an (9milion) naira ni
won fi kan iranse Olorun naa to je pasito eka ijo RCCG ti Ikosi Parish, Ketu
District pe o ji lowo okan lara awon ayalegbe e, iyen Dokita Emeka Ugwunze.
Ohun ta a gbo ni pe se
ni Ishola Kolawole lo ogbon arekereke lati fi gba owo lowo Dokita Emeka to n
gbe nile e to wa ni agbegbe Gbagada pe oun fe e ta ile naa fun ni milionu lona
ogbon (20milion) naira.
Ko pe ti won ni Dokita
Emeka fi ko milionu mesan naira fun Kolawole, toun naa si ko awon iwe ile naa
sile. Leyin to ko awon iwe ile naa sile, to ku kawon mejeeji jo kowo bowe
adehun, ni won ni Kolawole na papa bora, ti ko seni to mo bo se rin.
Gbogbo igbiyanju la gbo
pe Emeka gba lati ri Kolawole sugbon to ja si pabo, eyi gan an lo je ko loo
foro naa to awon olopaa leti, tawon yen si bere sii wa, ko too di pe asiri e
pada tu si won lowo.
Lesekese towo te e ni
won loo foju e bale ejo, ko too di pe leyin opolopo iwadii ti adajo pase pe
kawon olopaa atawon agbejoro tubo se lati ri idi oro naa, ni won ri aridaju pe
looto ni Kolawole jebi awon esun ti won fi kan an.
Nigba to n gbe idajo
kale, Arabinrin O.A Adedayo pase pe ki Kolawole to n foruko Olorun boju loo
sewon osu mejidinlogun pelu ise asekara, bee ni ko fi aaye sile lati gba beeli
e.
AWIKONKO tun gbo pe
yato si esun ti won fi kan an yii, won ni esun kan naa si wa ti Kolawole tun n
je lowo nile ejo kan, eyi ti won loo lo yi iwe osibitu lati fi paro pe oun wa
nile iwosan fun ojo pipe, eyi ti asiri e pada tu pe iro ni.
Bee la tun gbo pe ewon
ti adajo ju Kolawole si, ko die sun ti won fi kan an tele lowo pe ko ma yoju
sile ejo. Won ni lati ogba ewon lawon olopaa yoo ti maa gbe lo sile ejo.
No comments:
Post a Comment