IDIJE CHAMPION'S LEAGUE: SERGIO LO KO BA LIVERPOOL - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 27, 2018

IDIJE CHAMPION'S LEAGUE: SERGIO LO KO BA LIVERPOOL

Titi di bi e ti n kan iroyin yipo awon ololufe egbe agbaboolu Liverpool kaakiri agbaye ni won si n kanminu pupo lori bi agbaboolu egbe Real Madrid, Sergio Ramos se fipa se Mohammed Sallah lese, to si je pe ki ogbon iseju ti won bere idije asekagba (final) ni won yo Sallah danu.


Idije naa to pari si aami ayo meta si ookan (3-1) ti won gba ni papa isere Olympic, niluu Kiev, iyen lorileede Ukraine lojo Satide to koja yi la gbo pe ko dun mo awon omo egbe agbaboolu Liverpool ninu rara pelu nnkan to sele lori papa.

Ohun to daju ni pe, Sallah nikan lawon omo egbe atawon ololufe Liverpool gbokan le pe yoo je ki won ri ife eye (Trophy) naa gba, sugbon ti oro naa pada yi mo won lowo.

Akonimoogba egbe agbaboolu Liverpool, Jurgen Klopp nigba to n soro so pe ifarapa nla ni Sallah farapa lakoko toun ati Ramos jo n du boolu, to si je pe lati ori papa isere naa lo ti gba de osibitu lati ya X-Ray, to si tun si n gba itoju lowo.

Nigba to n kanminu soro, o so pe kii se nnkan to daa rara pelu iwa ti Sergio hu si Sallah lakoko ti won wa lori papa, to si je pe oun gan an lo fa a ti won ko fi gbegba oroke nibi idije naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI