‘Ise
esu ni, a ko nii se iru e mo’ loro ebe to n jade lenu awon baale ile meta towo
olopaa ipinle Ogun te niluu Ode-Remo lojo fraide to koja lo lohun, iyen ojo
ketadinlogbon osu to koja lakoko ti won loo ja ileese MTN lole.
Balogun
Lukman, eni odun mejidinlogoji (38) to gbe ni ojule keta, adugbo K & S; Sunday Kayode, eni odun mokandilogoji (39), to n
gbe lagbegbe Isheri ati Atanda Abiodun toun n gbe lojule keedogbon,
Egbeda/Akowonjo Road, Bakery bus-stop Lagos lowo te naa
AWIKONKO
gbo pe ni nnkan bi aago meji oru lasiri won tu sawon eso alaabo fijilante lowo
nibi ero alatagba (mast) ileese MTN, ti won si tawon olopaa lolobo lesekese,
tawon naa si gbera lati loo koju won.
Bi won
se foju kan awon olopaa lawon odaran maraarun na papa bora, towo si pada te
meta ninu won pelu batiri nla meta ati nnkan ti won fi n ge waya.
Agbenuso
fawon olopaa Abimbola Oyeye to fidi isele naa mule so pe komisana won, Ahmed
Iliyasu ti pase pe ki iwadi tesiwaju, leyin iwadii ni ki won loo foju won bale
ejo
No comments:
Post a Comment