Ilo ninu atejade to gbe jade laaro oni lati fi sayeye ayajo ojo awon omode lorileede Naijiria so nipa orisirisi adojuko tawon omode dojuko leka eto aabo, paapaa lorileede yii.
O gbawon obi, alagbato, ijoba atawon otokunlu lamoran pe ki won rii daju pe eto aabo ati alaafia je won logun pupo, ki won si mu gege bi ojuse nipa mi mu lokunkundun.
Enjinia Ilo so pe ojuse obi ati alagbato ni lati ko awon omode lekoo to kooro, ki won le fi wulo fun ojo iwaju won, paapaa orileede Naijiria leka eto ti won ba ti ba ara won.
O ni ki won rii daju pe awon agbegbe tawon omode n sere, ti won n ko eko ati bee bee lo ni ki won ri daju pe eto aabo to peye wa fun won.
Nigba to n gboriyin fun Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun, Ilo so pe ipa ti Gomina Amosun n ko lori eto eko, paapaa nipa abojuto awon omode nipinle Ogun ko se e bu kere rara, nitori pe ko si elegbe e lorileede Naijiria.
No comments:
Post a Comment