E GBA MI LOWO FAYOSE O, FAYEMI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 20, 2018

E GBA MI LOWO FAYOSE O, FAYEMI PARIWO SITA

Ileese eto ipolongo idibo fun Minisita foro ohun elo idagbasoke alumoni (Mines and Steel Development) lorileede Naijiria, Ogbeni Kayode Fayemi ti pariwo sita fawon omo orileede yi pe ki won gba oun lowo Gomina ipinle naa, Ayodele Fayose.

Ohun ta a gbo ni pe, asiri kan ti won loo lu sita pe Gomina Fayose fe e lo ogbon alumokoroyi lati fi ori gomina ipinle naa tele ri, Ogbeni Segun Oni ati Ogbeni Kayode Fayemi gba ara won latari bi won se loo gbe awon omoota dide lati fi da nnkan ru.

Ninu atejade ti Ogbeni Yinka Oyebode to ke agbenuso fun Fayemi gbe sita lojo Satide ano, o je ko di mi mo pe gbogbo asiri ti Fayose n se labele lati lo awon omoota lodi si Segun Oni, ki won si le ro pe Fayemi lo wa nidi e lo ti lu sawon lowo.

Oyebode so pe bo tile je pe won ti pari ise lori awon ohun elo ti won fe e lo lati fi dabaru nnkan, iyen awon aso ti won ko oruko Fayemi (JKF) si, ti won fe e fi sise buruku won ni won ti pin fun awon osise ibi naa, sugbon tasiri won ti pada tu sita.

O wa rawo ebe sawon osise eleto aabo kaakiri ipinle naa, paapaa lorileede Naijiria pe ki won tete bawon wa ona lati kapa Gomina Fayose, lati ma le se awon eeyan nijamba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI