Yoruba
bo, won ni ojo gbogbo ni t'ole, ojo kan soso ni t'olohun, eyi gan an lo
lo nibamu pelu basiri awon ayederu soja meta ti won n lu awon araalu ni
jibiti se tu, ti won si ti n ka boroboro bi eye awoko ni tesan olopaa
bayii.
Abayomi
Amos Akanji, Adebayo Rasheed Oladimeji ati Lawal Musa Akinmoye la gbo
pe won da awon araalu laamu, ti won si n fipa gbowo lowo won ladugbo
Adatan si Bode-Olude niluu Abeokuta, asiko ti won n fipa gbowo lowo
okunrin olokada kan lowo te okan lara won.
Kii
se pe asiri won dee de tu sawon olopaa lowo, ohun ta a gbo ni awon
araalu to fura si won pe ayederu ni won ni won loo ta awon olopaa
lolobo, ti oga olopaa Adatan, Ogbeni Joshua Olajide si ran awon omose e
lati loo sewadi won.
Nigba
tasiri won maa tu, Abayomi lowo koko te lojo Tusde ose to lo lohun,
iyen lojo ketadinlogun osu yi, nigba ti won ri ninu aso soja ti ko
soruko lara e, lo mu ki won bere sii foro wa a lenu wo, ti ko si le
dahun awon ibeere naa.
Bo
se fe e salo lawon olopaa naa ba fibon hale mon on pe awon yoo fibon fo
lese, ko too duro pe ki won se oun jeje, ati atimu lo sun oun debe
nitori pe opolopo ise lojn gbiyanju lati se sigbon ti ko si ona abayo.
O
ni je ko di mi mo fawon olopaa pe oun nikan ko loun n sise naa, awon
meta ni, ati pe se loun ji aso naa ka lori waya nigba toun loo ki enikan
ni baraaki awon sona, oun si ti fi gbowo repete lowo awon eeyan nitori
won ko mo pe oun ko kose naa rara.
Leyin
ose kan gbako, iyen lojo Tusde to koja yi lowo to o sese te Rasheed ati
Lawal lakoko tawon naa n lu jibiti lati gbowo lowo awon eeyan to n koja
lo.
AWIKONKO gbo pe se lawon eeyan bere sii fepe rabande-rabande ranse si won
nigba towo olopaa te won nitori ta a gbo pe won tun n fipa gbowo lawon
ileepo kaakiri, paapaa lasiko owongogo epo pentiroolu ki won to o le je
ki moto tabi okada wole ra epo.
Lesekese
tiroyin naa ti kan si Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa lo ti pase pe
oun fe e foju kan won, nigba to si ri won lo ni o see se ki won tun ti
hu awon iwa odaran min in, nitori naa lo fi so pe ki won tare won si eka
ileese won to n sewadi odaran, iyen CIID lati tubo foro wa won lenu wo
daadaa.
Bee
lo so fun won pe iwadii naa ko gbodo pe ki won too lo foju won bale
ejo. O wa ro awon araalu pe ki won ma se maa so pe ko si nnkan to kan
won nigba ti won ba kofiri awon afurasi odaran, eyi ti ko ni je ki won
fi to ileese olopaa leti nitori pe alaafia ilu, aabo emi ati dukia awon
araalu lo je won logun pupo, toun ko si ni faaye gba iwa odaran lasiko
toun ba si n je oga olopaa.
No comments:
Post a Comment