Aanu aje yoo fe e le seeyan bo ba gbo bi
gbajugbaja agba oni tiata nni, Alaaji Kareem Adepoju topo awon eeyan mo si Baba
Wande se n soro, to so pe awon maketa ni ko je koun ti gbe sinima jade, nitori
pe se ni won le oun danu tefe-tefe.
Lose to koja yi ni Baba Wande b’AWIKOKO
soro niluu Abeokuta, to si fe e le maa yo omi loju lakoko to n dahun ibeere olokan-o-jokan paapaa bo tun se sa
seyin nidi ise tiata, ti ko si tun ti gbe sinima jade bii ti tele mo.
O ni opo fiimu tawon n gbe jade lo je pe owo
ele lawon lo n ya lati fi se e, igba tawon ba si pari e tan lawon maketa yoo
tun je awon lowo, ti won ko nii san owo fun won, to je pe se lawon yoo tun sese
maa gbe ara won lo sile ejo kawon too le ri owo won gba diedie.
Ninu
oro e, o so pe “Mi o le si se fiimu mo
fawon maketa, nitori pe mi o le loo ya owo fi se fiimu lai jere e. Ki
nni yoo je eere mi, nigba ti mo ba se fiimu, ti mo gbe e fun
maketa, to je pe se ni won a tun je mi lowo, ti mi o pa owo lori e.
Nigba ti a ba ta fiimu, ti a ko ri owo gba, to di pe a bere sii gbe ara
wa lo sile ejo. Mi o
tun le loo ya owo fi se fiimu jade mo, ko wa je pe maketa lo maa je
gbogbo eere
to wa nibe to ye ki n je.
“Won yan mi je ninu fiimu Ti Oluwa Nile, to
je pe awon ta a jo se e lo jeere e, won ko je ki awa ta a kopa to joju jeere e.
Eyi ta a tun se funra wa, awon maketa tun je wa lowo. Kii se oro awon to n se ayederu
ni won ko je ka jeere rara, eyi ti awa arawa n se funra wa lo po ju, ko da to
ju ti awon to n se ayederu lo. Ijoba ko le da si, nitori pe ijoba gan an mo
nnkan to n sele.
“Mo dupe pe latigba ti mi o ti se fiimu jade,
ebi ko pa mi. Mo tun ti n dogbon lati ya ise min in, ki n si ta a funra mi, ko
da, Olorun tun ti fi ona tuntun han mi lati maa gbe fiimu jade funra mi. Ori
ero ayelujara ni opo fiimu mi yoo maa wa, iyen lori Baba Wande TV ni YouTube.”
Nigba to n soro isokan laarin awon oni tiata
elegbe e, o ni ayipada rere ti n wa nitori pe leyin ti Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi
ti ba won da si lodun to koja lawon ti n ba ara won se po pada bii ti tele, ati pe oun ati
Dele Odule tun ti pada di ore, tawon ko si le se kawon ma soro.
No comments:
Post a Comment