ADURA NI NAIJIRIA NILO KII SE EPE - SOGBEIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 29, 2018

ADURA NI NAIJIRIA NILO KII SE EPE - SOGBEIN

Onorebu, Arabinrin Yetunde Sogbein to n soju agbegbe Odeda nile igbimo asoju-sofin nipinle Ogun ti gbawon omo orileede Naijiria lamoran pe ki won tubo maa gbadura fun orileede yi, dipo ki won maa fi epe orisirisi ranse sawon adari won.

 


Sogbein lo soro yi laaro onii nigba ninu atejade to gbe jade fawon oniroyin lati fi saami ayeye ayajo ojo eto isejoba awaarawa fun todun 2018 lati owo akowe eto iroyin e.

 

O ni oye ki maa wo awokose awon ara ile Amerika to je pe bi won ba ji laaro, oun akoko ti won yoo koko so nip e ki Olorun bukun fun Amerika, iyen God Bless America nitori pe adura je oun kan Pataki to maa n yi itan pada si rere.

 

Bee lo sapejuwe orileede Naijiria gege bi orileede to kun fun waara ati oyin, pelu awon ohun amusoro ti Olorun fi jinkii e, eyi to mu ko wa lara awon orileede ti gbogbo agbaye n kan saara si nipa eto oro aje.

 

Sogbein so pe o ye kawon omo orileede Naijiria to mo nnkan ti won n se maa toju orileede won to ba je pe looto ni won feran e, ki won si maa gbe e ga ni gbogbo ibi ti won ba kaakiri agbaye.

 

O ni pelu awon ohun amusoro ati amusagbara ta a ni lorileede yi, ko ye kawon omo orileede yi tun maa gbe ninu osi, iya, ofo ati airije ti a n koju lasiko yi, sugbon o seni laanu pe awon adari ti a tin i koja lo ni won ko mo Pataki nnkan ti a ni, ti won si ko wa sinu ila-ilo ta n koju lasiko yi.

 

Nigba to n sapejuwe ijoba Buhari, Sogbein so pe ise takun-takun ni ijoba Muhammadu Buhari pelu igbakeji e, Ojogbon Yemi Osinbajo n se lati rii daju pe ibikibi tawon omo orileede ba wan i agbaye ni won yoo le fowo soya pe omo Naijiria lawon lai tiju.

 

Bakan naa nipa isejoba Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun, Onorebu to n soju agbegbe Odeda naa so pe ipa ti gomina ti la sile ko see pare titi lai, nitori pe awon awon aseyori manigbagbe lawon nnkan to ti se.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI