Adigunjale pade iku ojiji lakoko to ja foonu gba nipinle Delta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 8, 2018

Adigunjale pade iku ojiji lakoko to ja foonu gba nipinle Delta

Se lawon ara adugbo Oche to wa niluu Benin, ipinle Edo gba ilu ti won si bere sii korin ope nigba towo awon eso alaabo ilu, iyen Fijilante Group of Nigeria te okan lara awon ogbologbo adigunjale kan, ti won si yinbon pa a lesekese.

Ojo Satide to lo lohun, iyen ojo kejidinlogbon osu to koja yi la gbo pe gendekunrin naa ti won ni oun atawon emewa e ko nise meji ju ki won maa digun gba foonu lowo awon ara abule lo tun loo fibon ja foonu gba, to si gbabe pade iku ojiji.

Gege bi awon to gbe iroyin isele naa si AWIKONKO leti, won ni kii se eni to pade iku ojiji yi nikan lo loo sise lojo naa, won ni oun ati ore e kan ni won jo loo fi okada gba foonu, ati pe nigba ti won ja baagi gba lowo omobinrin kan, tiyen si pariwo sita ko too di pe awon osise Fijilante sare jade ni won ti yinbon fun won sugbon to je pe gendekunrin yi nibon ba, lo mu ki ore e na papa bora.


Awon osise Fijilante yi la gbo pe won loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si pada gbe oku e lo si mosuari, bee ni won gbe okada ti won gba lowo won loo si tesan won.

Ohun ta a gbo ni pe iwadii si n lo lowo lati mu awon odaran to ku ti won maa n fojoojumo ja foonu gba lowo awon araabule naa.

Capt; Oku e ati okada ti won gba lowo e

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI