Pasito Senfuye ba idile Ojogbon Adedeji kedun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 29, 2018

Pasito Senfuye ba idile Ojogbon Adedeji kedun

Oludasile soosi Treasure House of God, Pasito Oluseye Senfuye ti ba idile Ojogbon Adebayo Adedeji kedun lori bi baba naa se ta teru nipa leni odun metadinlaadorun (87) lojo Wesde to koja yi.

Ninu atejade ti Ogbeni Adeniyi Adeloye, eni to je gege bi adari eka iroyin fun Pasito Senfuye fi ranse si AWIKONKO losan oni, o je ko di mi mo pe ogbontarigi to ti kopa to joju lorileede Naijiria, paapaa leka eto okoowo (Economics) nigba aye e.

Ojise Olorun Senfuye nigba to n sapejuwe oloogbe Ojogbon Adedeji, o so pe ipa to ti ko lorileede yi ko see gbagbe nitori pe pelu bo se fi gbogbo agbara e lati sin in orileede Naijiria, ile adulawo (Afrika) atawon ilu min in kaakiri agbaye.

Ninu atejade naa, o ni okan pataki yo ja takun-takun ni eka eto oro aje tawon eeyan kaakiri agbaye si n gbosuba kare fun un ko to o jade laye latari awon ona ara oto to n gbe ise e gba, paapaa to tun je okan pataki lara awon to da sin sin ile baba eni tawon akekoo jade maa n se, iyen National Youth Service Corps (NYSC).

Bee lo tun je ko di mi mo ninu oro e pe "Bo tile je pe iku Ojogbon Adedeji je ibanuje nla, sibe awon ipa to fi sile ko ni se e gbagbe, nitori pe yoo tun je kawon eeyan to n bo leyin tele."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI