Lonii ojo Aiku Sande nileese olopaa ipinle Ogun kede sita pe owo awon ti te awon odaran marun un otooto to je pe won ko nise meji ju ki won maa ta owo naira ta n na lorileede yii, eyi to tako ofin ile ifowopamo apapo ile yii, iyen Central Bank.
Awon maraarun |
Ojo Tosde ojo kejila ati ojo Fraide, ojo ketala osu yi la gbo pe owo te Toyin Alegbe, Kehinde Akinbode, Soneye Latifat, Kehinde Olanrewaju ati Iyanuoluwa shokunbi la gbo pe owo te niluu Abeokuta, Ijebu ode ati Sagamu lakoko ti won polowo owo naira kaakiri awon adugbo.
Bo tile je pe kii se pe awon eeyan yoo sese maa ta owo kaakiri ode ariya, sugbon lodun 2007 la gbo pe ijoba apapo ti fofin de iru awon bee pe.ko tun seni to gbodo maa ta owo ta n na lorileede yii mo, ti won si so o di ofin.
Sugbon nnkan to tun je koro awon marun un towo te yi maa se opo awon to gbo sii ni pe kii se ode ariya lowo ti won, asiko ti won n kiri owo naa kaakiri awon adugbo bi eni ta buredi lowo te won.
Ohun ta a gbo ni pe owo ti won ri gba lowo awon maraarun un naa ko din ni milionu kan aabo (1,560,000) naira lasiko towo te won.
Nigba to n soro, Abimbola Oyeyemi to je alukoro fawon olopaa je ko di mimo pe ese tawon eeyan naa se tako ofin ile ifowopamo apapo wa ti abala kokanlelogun akoko (Section 21(1)) ti won gbe kale lodun 2007, eyi to so ni pa sise owo wa nisekuse.
O so pe lesekese ti Komisana won ti gbo, iyen Ahmed Iliyasu lo ti pase pe ki won tare won si eka ileese won n ri soro odaran (SCIID) lati sewadi awon eeyan naa, kowo ba a le te awon min in ti won tun hu iru iwa bee lawujo.
Bee lo tun je ko di mimo pe Iliyasu kilo fawon araalu lati yera fun iru awon iwa bayii to le maa ta abuku ba orileede, paapaa nipa sise owo nisekuse nitori pe aami idanimo wa ni owo naira je.
No comments:
Post a Comment