Opo awon ti won ti n gbo ipolowo naa lori redio ati telifisan kaakiri orileede Naijiria ni won ti n foju sona lati je anfaani alailegbe, eyi ti ileese kan to nife awon araalu, paapaa awon osise feyinti lenu ise gbe kale.
Gege bi a se gbo, ileese kan ti won pe ni Business Development and Support Services pelu ajosepo Business Executives International ni won gbe idanilekoo olojo kan kale fawon osise feyinti atawon to n foju sona lati feyinti, yala lenu ise ijoba tabi aladani.
Ohun ta a gbo pe ojo Abameta Satide, iyen ojo kokanlelogun osu kerin ti a wa yi (Saturday, April 21, 2018) ni Idanilekoo naa ti won pe akori e ni Pataki Ifeyinti Ninu Eto Oro Aje To Ni Adojuko, iyen ni pe Essence Of Retirement In A Challenged Economy.
Pataki idanilekoo naa ni lati je kawon osise feyinti mo awon ona ti won le gba lati maa ri owo, dipo ki won lo maa jokoo senu ona ileese ijoba fun owo ifeyinti won, ti asiko ifeyinti won yoo si di irorun fun won.
Gege bi a ti mo pe ogunlogo awon osise feyinti lo je pe won kii ni ifokanbale latari bi ijoba kii se e tete fun won lowo ifeyinti won, eyi to maa n mu won paara ileese ijoba lati ja gba owo ti won fi odun marundinlogoji (35) sise fun.
Nigba to n gba enu awon alase ileese naa soro, Ogbeni Kolawole Adejojo tawon eeyan tun mo si Kasnaty, o so pe ipo ti orileede yi wa lasiko yi, paapaa owo tijoba fi mu awon osise feyinti lo je kawon alase ileese naa ronu ona ti won le gba ran awon araalu lowo.
Kasnaty je ko di mimo pe Idanilekoo olojo kan soso naa kii se pe won gbe e kale lati fi pawo wole sapo ileese naa, nitori pe ofe (free) lawon akopa yoo fi wole sinu gbongan ti idanilekoo naa yoo ti waye, nitori pe won fe kawon eeyan, paapaa awon osise feyinti mo awon ona ti won le gba lati maa ri lojoojumo, ti won si le fi da ise kekere sile laaye ara won.
Soobu itaja igbalode ti Atobatele to wa ni Imo, niluu Abeokuta (Atobatele Complex, 68, Awolowo Avenue, Imo Abeokuta, Ogun State) ni eto naa yoo ti waye laago mewaa aaro.
Okunrin gbajumo sorosoro naa tun je ka mo pe lara awon nnkan ti won fe e dawon eeyan lekoo lori e lojo naa ni Bi a se le gbe igbese lati wonu ifeyinti (How to plan your retirement), Gbigbarukuti ise okoowo ati oro iyanju (Business Support and Advice) ati Lila awon eeyan loju sawon anfaani to wa ninu okoowo (Exposure to Opportunities in Business and Investment).
AWIKONKO tun gbo pe opo awo onise aladani nla atawon onisowo ti won ti gbajumo laarin awujo ni won maa wa nikale lojo naa la ti bawon akopa soro, ti won yoo si tun gba won niyanju.
No comments:
Post a Comment