Pelu
ebe ni bale ile kan, Ogbeni Aremu Onikeku fi n soro nile ejo kokokoko to wa ni
Ake niluu Abeokuta lai pe yi pe ki ile ejo tu igbeyawo ogun odun to wa laarin
oun atiyawo oun, Arabinrin Olubunmi Onikeku nitori pe kii ba oun fo aso, ko si
tun ni da ina ounje foun.
Bale ile naa
to so pe bo tile je pe ounje niyawo oun to bimo repete foun, sibe ko si ojo kan
to dana ounje nile foun ri, to si maa so pe koun wa maa jeun ninu ounje toun n
ta, sugbon to so pe ara oun ko gba a mo.
Okunrin naa
so pe orisirisi okunrin lo n tele iyawo oun. O tun niyawo oun ti so omo akobi
oun to n je Kemi di alagbere, to je pe ko seni ti ko le ba omo naa sun ladugbo,
ko da to so pe won ti n pe omo naa ni aja ladugbo.
O nigba to
su oun loun mu Kemi akobi oun lodo mama oun lati lo maa gbe nitori itiju,
sugbon tomo naa sa kuro nibe pelu ajoso oun atiyawo oun, ti won ko si je koun
gbo. Aremu ni eyi tiyawo oun se to tun dun oun ju nib o se ki iya to bi oun
mole, to si bere sii lu nigba toun ko si nile, sugbon toun pada de ba won nibi
tawon aaraadugbo ti pe le won lori.
Ninu oro iyale ile naa, Arabinrin Olubunmi Onikeku so pe iro to jinna si
otito oro ni oko oun n pa nitori pe oun gan an lo n da wahala sile nile, to si
tun ti ko gbogbo eru e kuro nile lati lo maa gbe soosi.
Obinrin naa loun ko figba kan na iya oko oun, nitori lojo kan niya oko
oun wa a ba oun nile, to si bere sii se epe nlanla foun atawon omo oun, awon
araadugbo ni won n ba oun bebe lojo naa pe ki iya agba naa yee sepe mo.
O ni iya agba naa lo gba oun leti, to si tun yi oun mole ninu igbo, ibe
ni oko oun ti baa won lojo naa, to si bere sii so pe se loun n na iya oun, to
si je pe ori oun niya e wa lojo naa.
Bakan naa lo so pe bo tile je pe oko oun maa n gbo bukata lori awon omo
e, sugbon ti kii foun lowo nigba toun ba ti nilo owo, sibe awon iwa igberaga e
lo n da ile wa ru pelu bo tun se lo n gbe soosi.
Nigba ti awon onidajo mejeeji, Oloye Akande ati igbakeji e, Onarebu
Majekodunmi n beere lowo won pe kinni nkan ti won fe, Ogbeni Aremu so pe oun ko
le ba iyawo oun gbe mo, sugbon toun yoo maa gbo bukata lori awon omo oun bii ti
tele, sugbon ti obinrin naa so pe iwa oko oun ko ba toun mu mo, bo tile je pe
ko sibi toun fe e lo, nitori pe oun ko bimo feni meji.
Awon onidajo mejeeji wa a ro won pe ki won tun loo soro naa ni tubinubi
nijokoo molebi, ki won si pada wa lojo ketala osu yi lati gbo esi. Won ni bi ko
ba si ayipada rere tawon mejeeji si n fe ko ara won sile, dandan ni kawon ya
won pelu ofin.
No comments:
Post a Comment