Bi toko tiyawo ti won tun je iranse Olorun ko
ba tete mura si oro ara won ko too di ogunjo osu kerin ti a wa yi, o see se ki
ileejo koko-koko to wa ni Ake niluu Abeokuta tu won ka pelu bawon mejeeji se so
pe iwa ara won ko ba ara won mu mo, nitori naa, ki ileejo naa tu igbeyawo odun
mejo to wa laarin won ka.
Lojo Isegun Tusde ose to koja lo lohun ni iyaale
ile naa, Arabinrin Regina Babatunde gbe oko e to je iranse Olorun, Ogbeni
Ayinde Babatunde lo siwaju awon adajo, to si n bebe pe ki ile ejo naa tu
igbeyawo won ka, bee lo tun be ile ejo pe ko ba oun gba omo kan soso toun bi
fun oko oun lowo e.
Nigba to n ka awon esun to fi kan oko e
niwaju awon adajo mejeeji, iyen Oloye Akande O.O ati Onarebu Arabinrin
Majekodunmi H.I, Regina so pe iwa toko oun n hu soun ko ba toun mu mo, ti ara
oun ko si gba a mo gege bi obinrin, nitori pe opo igba lo maa n lu oun, ti ko
sit un ni foun lowo ounje.
Iyaale ile eni odun mejilelogoji (42) to so
pe ile ounje igbalode kan loun ti n sise naa tun so pe igba kan wa ti oko oun
ti le oun jade fojo meta ri, to je pe odo araadugbo loun lo sun, ki won too ba
won pari e, bee lo so pe oko oun tun le oun jade fosu meta, ti ko beere laafia
oun ati omo oun, o lawon ebi lo bawon pari e.
Obinrin naa so pe nnkan to tun fa a toun fi
wa sile ejo ni bi oko oun se le oun jade kuro nile, to si gba omo lowo oun, to
lo gbe e fun un awon obinrin meji kan, Bose ati Funmilayo ti won kii se ebi e
rara, tawon yen si n fiya je omo oun, ko da to so pe Funmilayo ti fe e na oun
lojo kan nitori toun loo wo omo naa nile won.
Nigba toun naa n soro, Baale ile naa to so pe
iyen Salesman loun n se so pe nigba toun fe Regina loun ti ba Olorun da majemu
pe oun ko nii ko enu ife si obinrin miran laye oun mo, to si je pe Olorun le
jeri oun.
Ayinde so pe esun tiyawo oun fi kan oun ni pe
nise loun n yan ale, ko da, to tun so pe oun ti bimo sita. O niyawo oun ti loo
fejo sun aburo oun kan to n gbe l’Ekoo, to si tun n ba oun loruko je kaakiri
pelu boun se je iranse Olorun.
Okunrin naa so pe nigba ti wahala naa maa
koko bere, aburo iyawo e lo so pe o fee se idanwo asekagba, iyen WAEC, toun si
so pe ko je komo naa wa maa gbe lodo won, sugbon tiyawo oun so pe se loun n ba
omo naa sun.
Nipa awon ti Regina so pe omo wa lodo e,
Ayinde ni ile Bose ati Funmilayo loun gbe nigba toun lo sise niluu Ibadan, nibe
loun ti mo won ti won si se daadaa soun, lo je koun mu omo naa lo sodo won lati
maa gbe, toun si lo n fomo naa lowo ounje ni gbogbo ipari ose.
Awon onidajo mejeeji, Oloye Akande ati
igbakeji Onarebu Majekodunmi nigba ti won n beere pe kin i won fe e, se lawon
mejeeji so pea won ko le pada di loko-laya mo lailai, nitori konikaluku maa lo.
Oloye Akande ati igbakeji e so pe bo tile je
pe ofin ko faaye gba won lati tu won ka lojo kan soso ti won ba koko gbe ejo
wa, sugbon ki won pada wa logunjo osu yi, bi ko bas i ayipada, awon yoo gbe
igbese to ba ye.
No comments:
Post a Comment